Fọlọrunsho kọja aaye ẹ, adajọ ti ni ko lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn Kirikiri

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ O.M Ajayi, tile-ẹjọ Majisireeti kan to wa niluu Ebute-Mẹta, nipinlẹ Eko, ni wọn foju Ọgbẹni Jẹgẹdẹ Fọlọrunshọ, ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta to fipa ba ọmọ ọdun mẹjọ sun si.

ALAROYE gbọ pe ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, ọdun yii ni afurasi ọdaran ọhun fipa ba ọmọ-ọdun mẹjọ naa sun l’Ojule kẹrin, Opopona Adegbitẹ, niluu Mushin, ipinlẹ Eko.

Ọlọpaa olupẹjọ, Paul Ugorji, to foju olujẹjọ bale-ẹjọ sọ fun adajọ pe ko ma gbọrọ lẹnu olujẹjọ rara, ko si paṣẹ pe ko wa lọgba ẹwọn tawọn ti mu un wa, nitori pe awọn gbọdọ kọkọ mu ẹda iwe ipẹjọ rẹ lọ sọdọ ajọ to n ri si lilo ọmọde nilokulo niluu Eko, ‘Directorate Of Public Prosecution’, fun ojulowo amọran.

Olupẹjọ ni, ‘Oluwa mi, awọn ọlọpaa teṣan agbegbe Mushin, ni wọn lọọ fọwọ ofin mu olujẹjọ yii lẹyin ti wọn lọọ fẹjọ rẹ sun wọn, loju-ẹsẹ ni wọn ti taari ẹjọ ọhun lọ si olu-ileeṣẹ ọlọpaa kan to wa ni Yaba, nipinlẹ Eko, fun iwadii to peye. Gbogbo ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ pata lo jẹbi rẹ, ti ofin ilu Eko ko si faaye gba a rara.

Bakan naa ni ọlọpaa olupẹjọ fi awọn ẹri kọọkan han adajọ ile-ẹjọ naa eyi to sọ pe, funra olujẹjọ lo sọ fawọn ọlọpaa pe oun fipa ba ọmọ naa sun.

Nigba to maa gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ ni ki wọn lọọ fi olujẹjọ sọgba ẹwọn Ikoyi, titi ọjọ ti igbẹjọ maa too waye nipa ẹjọ rẹ.

Leave a Reply