Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọga agba ajọ to n mojuto igboke-gbodo ọkọ loju popo, FRSC, nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Jonathan Ọwọade, ti ṣekilọ fawọn awakọ ero pe ibudokọ yoowu ti ko ba tẹle ilana Covid-19 lasiko pọpọsinsin ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun yoo di titi.
Ọwọade sọrọ ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, niluu Ilọrin, lasiko to n ṣalaye nipa igbaradi ajọ naa lati mu irin ọkọ ja gaara.
O ni awọn ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ Korona, nitori naa, gbogbo awọn awakọ atawọn ero inu ọkọ ni wọn gbọdọ tẹle ilana tijọba apapọ pa nipa lilo ibomu ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O rọ awọn ẹgbẹ awakọ lati pa awọn ofin gbigbe ero niwọnba ati kikan an nipa fun awọn ero lati lo ibomu.
“Ijọba ti fun wa laṣẹ lati ti ibudokọ ti ko ba tẹle ilana ati ofin Covid-19 ati ofin irinna ọkọ pa. Asiko ọdun la n wọ yii, oriṣiriiṣii eeyan ni yoo si maa rọ wọle, a ni lati ṣọra ṣe, ka si pa gbogbo ofin mọ.”
Ọwọade gba awọn awakọ nimọran lati ri i pe wọn ṣe awọn atunṣe to ba yẹ lara ọkọ ko too di pe wọn gbe e soju titi.
Bakan naa, o ṣekilọ pe ko gbọdọ si gbigbe ọkọ sẹgbẹẹ titi, nibi to le fa ijamba tabi fifi nnkan di nọmba ara ọkọ.
O tun gba awọn awakọ ero ati aladaani niyanju lati yẹ ilera ara wọn wo ko too di pe wọn bẹrẹ irin-ajo, ki wọn si ṣọra fun titẹ foonu tabi ipe lasiko ti wọn ba n wa ọkọ.
O fi kun un pe ẹgbẹrun meji oṣiṣẹ FRSC lawọn ti da sita lati ri i pe lilọ-bibọ ọkọ loju titi lọ geere. O rọ araalu lati pe nọmba pajawiri, 122, ti iṣẹlẹ pajawiri kan ba ṣẹlẹ loju titi kawọn le tete debẹ.
O ni ajọ FRSC yoo jọ ṣiṣẹ papọ pẹlu ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Kwara to n mojuto eto irinna, KWARTMA, ọlọpaa, NSCDC lasiko ọdun.