Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Iyawo igbakeji aarẹ orilẹ-ede yii nigba kan, to tun jẹ oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Alaburada (PDP), Abilekọ Titi Atiku, ti yọ ọkọ rẹ, Alaaji Atiku Abubakar, foda kuro ninu ẹya awọn Fulani to n pa awọn eeyan nipakupa ni Naijiria lọwọlọwọ.
Titi sọrọ yii lasiko iṣide eto ipolongo ibo ẹgbẹ PDP to waye niluu Akurẹ, t ii ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla yii.
Ọmọ bibi ilu Iloko Ìjẹ̀ṣà, nipinlẹ Ọṣun, ọhun ni oun n gba ẹnu ọkọ oun ṣeleri fawọn eeyan pe kiakia ni gbogbo ọrọ awọn Boko Haramu yoo dopin ni kete ti ọkọ oun ba ti gba ìijọba, ti eto ẹkọ-ọfẹ yoo si wa fun tẹru-tọmọ nilẹ Naijiria.
O ni ọrọ iṣejọba orilẹ-ede yii ko ṣe ajeji rara si baale oun, nitori ohun to ti ṣe ri ti ko si bu u lọwọ ni. Ọpọ awọn ti wọn ti di alagbara ninu eto oṣelu Naijiria lonii bii Nasir El-Rufai to jẹ Gomina ipinlẹ Kaduna lọwọlọwọ ati Ọmọwe Ngozi Okonjo-Iweala lo ni Atiku lo mọ bi wọn ṣe darapọ mọ ijọba Oluṣẹgun Ọbasanjọ.
Iyawo Atiku ni ko si ani-ani pe Atiku lo wọle ninu eto idibo aarẹ to waye lọdun 2019, ki ẹgbẹ oṣelu APC to wa nipo too fi eru gba ibukun mọ ọn lọwọ.
O ni o ti to asiko to yẹ kawọn ọmọ Yorùbá fọwọ sowọ pọ, ki wọn si fi ibo wọn gbe Alaaji Atiku wọle nitori pe ko si ọmọbìnrin Yorùbá kan to ti i de ipo obinrin akọkọ ri lati igba ti Naijiria ti gba ominira.
O rọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo ki wọn fọkan ara wọn balẹ lori ọrọ Atiku, nitori pe ewe rẹ ti pẹ lara ọsẹ awọn ọmọ Yorùbá, o ni oun ti kọ ọ ní ilana ati eto Yorùbá daadaa, o si ti mọ-ọn kọja afẹnusọ.
Lara awọn to peju pesẹ sibi eto ipolongo ọhun ni ẹni ti Atiku yan gẹ́gẹ́ bii igbakeji rẹ, to si tun jẹ Gomina ipinlẹ Delta lọwọlọwọ, Ifenayi Okowa, alaga gbogbogboo fẹgbẹ oṣelu PDP, Ọjọgbọn Iyorcha Ayu, gomina ti wọn ṣẹṣẹ bura wọle fun nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Udom Emmanuel, Gomina ipinlẹ Sokoto, Alaaji Aminu Tambuwa atawọn eeyan jankan jankan mi-in ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.