Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni awọn ọdọ tinu n bi ni agbegbe Danialu Oke, Gaa-Akanbi, niluu Ilọrin, mu ogbologboo adigunjale kan to n yọ agbegbe naa lẹnu, Aina Toheeb, lakooko to fo iganna wọle, to fẹẹ jale lagbegbe naa, ni wọn ba fa a le ọlọpaa lọwọ.
Ẹnikan lara olugbe agbegbe naa lo ri ọmọkunrin naa nigba to fo iganna wọnu ile kan, ẹni naa lo figbe ta, gbogbo araadugbo tu jade, wọn si n le adigunjale naa bo ṣe n sa lọ titi tọwọ fi tẹ ẹ. Toheeb ni wọn sọ pe o ti n daamu awọn araadugbo naa lọjọ to pẹ. Wọn ba baagi dudu kan ti oniruuru eroja to fi n fọle wa ninu rẹ lọwọ ẹ.
Bi wọn ṣe gba a mu tan ni wọn ja a sihooho, wọn de e lokun, ni wọn ba fa a le ọlọpaa lọwọ.