Gani Adams ṣefilọlẹ ẹṣọ alaabo Oodua ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ki eto aabo le gbo pọn si i ni Kwara, Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Iba Gani Adams, ti ṣe ifilọlẹ ẹṣọ alaabo Oodua niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, lọjọ Ẹti, Furaide.

Nigba ti Adams n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ọffa, o ni awọn ṣe ifilọlẹ ẹṣọ alaabo naa ki eto aabo le rajaja si i ni gbogbo ẹkun Guusu Iwọ Oorun Naijiria, ati ki wọn le daabo bo gbogbo ilẹ Yoruba ati gbogbo agbegbe rẹ. O tẹsiwaju pe Naijiria ti n koju ipenija eto aabo lati ọjọ pipẹ, ti ko si yọ ẹkun Guusu Iwọ-Oorun silẹ, idi niyi ti wọn fi gbe ẹṣọ alaabo naa dide.

O fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe ipinlẹ Kwara wa lara ẹkun Aarin-Gbungbun Naijiria, wọn tun wa lara ẹya Yoruba ti awọn ẹṣọ alaabo yoo maa ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn eyi to wa nilẹ tẹlẹ lawọn ijọba ibilẹ mẹrẹẹrindinlogun to so Kwara ro, ki aabo to peye le wa fun gbogbo olugbe ipinlẹ naa.

Adams, ni ẹṣọ alaabo Oodua ti n ṣiṣẹ lawọn ipinlẹ Yoruba bii Eko, Ogun, Ọyọ, Ọṣun, ti swọn si tun ṣe ifilọlẹ rẹ ni Kwara bayii, tori oun nigbagbọ pe ipinlẹ naa ṣe pataki si ilẹ Yoruba, ti yoo si di ipinlẹ alalaafia fun aabo to peye. O rọ ijọba Kwara atawọn ọba alaye ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ẹṣọ alaabo naa, ki wọn le ṣe aṣeyọri.

Leave a Reply