Adewale Adeoye
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku lorileede yii, ‘Economic And Financial Crimes Commission’ (EFCC), ti sọ ọ di mimọ pe gbara ti Gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle, ba ti fipo rẹ silẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lawọn maa fọwọ ofin mu un, ko le waa jẹjọ lori ẹsun iwa jibiti kan ti wọn fi kan an pe o aadoje biliọnu Naira (N70B), to jẹ owo ijọba ipinlẹ naa sapo ara rẹ. Wọn ni igbesẹ to gbe yii ko b’ofin mu rara, ijiya si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ.
Ajọ ọhun ni idi tawọn ṣe n duro de akoko ti Matawalle maa gbejọba silẹ ko too di pe awọn fọwọ ofin mu un ni pe ofin ko faaye gba ẹnikẹni lati pe gomina to ṣi wa lori aleefa lẹjọ, tabi ki wọn fọwọ ofin mu un. Ṣugbọn to ba ti kuro lo maa le waa jẹwọ bo ti ṣe ṣowo nla kan ti wọn lo poora ninu akanti ile ijọba rẹ fawọn.
Wọn ni gbogbo ohun to yẹ pata lawọn ti ṣe lori ọrọ naa bayii, ko si sọna kankan rara fun Matawalle lati ja bọ ninu ẹsun ikowojẹ tawọn fi kan an yii.
Ninu atẹjade kan ti EFCC fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni wọn ti sọ pe, ‘A n fi akoko yii sọ fun gbogbo ẹyin ara orileede yii pata pe mẹwaa yoo ṣẹlẹ ni gbara tawọn gomina kọọkan ba ti gbejọba wọn silẹ, ki i ṣe Matawalle nikan la maa fọwọ ofin mu, aimoye awọn kan lẹ maa gbọ pe wọn n jẹjọ ẹsun iwa ọdaran lọdọ wa. O fi kun un pe awọn ẹsun pẹẹpẹẹpẹ gbogbo ti Matawalle n fi kan alaga ajọ naa pata ki i ṣe tuntun, o di dandan ki ẹni ta a lu tara daadaa, o n wa ọna lati jajabọ ni, ko si le ja bọ rara, ibi to daa gidi la ti gba a mu bayii.
Awọn ẹri to daju wa lọwọ wa pe ọwọ rẹ ko mọ rara. Awọn owo kan wa to lọọ gba ni banki, to nijọba oun fẹẹ lo lati fi ṣe awọn iṣẹ idagbasoke kọọkan laarin ilu, ṣugbọn to jẹ pe ṣe lo da owo naa sapo ara rẹ. Eyi iṣẹ ko ṣe e, bẹẹ ni ko si owo to gba ọhun ninu apo ijọba ipinlẹ naa bayii.
A maa lọọ fọwọ ofin mu un nigba to ba gbe ijọba rẹ silẹ tan, ibi gbogbo ti owo naa gba lọ pata la ti mọ bayii, awọn ileeṣẹ agbaṣẹṣe-gbogbo to pin owo ọhun sinu akanti wọn la ti ri, awọn ileeṣẹ naa ti iye wọn to ọgọrun-un gba owo lọwọ rẹ, wọn ko ṣiṣẹ kankan fun ipinlẹ Zamfara ti wọn tori ẹ gba owo ọhun.
Ohun to ya ni lẹnu ju lọ nibẹ ni pe awọn kọngila kọọkan ta a ti fọrọ wa lẹnu wo ti jẹwọ pe loootọ lawọn gba owo lọwọ Matawalle, ṣugbọn to kan an nipa fawọn pe kawọn da gbogbo owo naa pada sinu akanti oun kan bayii to fun gbogbo wọn.
Kọngila kan niluu Abuja gba owo iṣẹ biliọnu mẹfa kan lara iṣẹ onibiliọnu mẹwaa lọwọ Matawalle, ṣugbọn ko ṣiṣẹ kankan fun ipinlẹ naa rara, o ti da awọn owo ọhun pada fun un.
ALAROYE gbọ pe gbara ti ajọ naa ti kede pe awọn yoo fọwọ ofin mu Matawalle to ba ti fipo silẹ nibẹru-bojo ati ipaya nla ti wa ninu ile ijọba ipinlẹ naa, ti ko sẹnikankan to mọ ohun to le ṣẹlẹ bayii.
Ṣa o, Matawalle paapaa ti sọ pe ki i ṣoun nikan lo yẹ ki wọn fẹsun iwa ibajẹ ati jibiti kan rara, o ni ṣe lo yẹ ki wọn ṣewadii alaga ajọ naa, Ọgbẹni Abdulrashid Bawa, daadaa, nitori pe ọwọ rẹ paapaa ko mọ rara nipa ẹsun ikowojẹ gbogbo.