Jọkẹ Amọri
Olori ẹgbẹ Ilana Oodua, Ọjọgbọn Banji Akitoye ti sọ pe gbogbo agbara to ba wa ni ikapa awọn lawọn maa lo lati ri i pe eto idibo ko waye lọdun 2023, afi tijọba apapọ ba pe ipade, nibi ti awọn oriṣiiriṣii ẹya lorileede yii yoo ti dibo lati sọ pe awọn ṣi fẹẹ wa lara Naijiria, abi awọn fẹẹ maa lọ lati da duro ni.
Dokita Don Pedro Obaseki lo gbẹnu ọjọgbọn yii sọrọ ọhun nibi ipade oniroyin kan ti ẹgbẹ to n ja fun ominira agbegbe wọn ti wọn pe ni Nigeria Indigenous Nationalities Alliance for Self-Determination (NINAS) ṣe niluu Eko lẹyin ti ọgọta ọjọ ti wọn fun ijọba apapọ lati pe ipade apero pe awọn fẹẹ ya kuro lara Naijiria ti pe.
Awọn ẹgbẹ yii sọ pe ki ẹnikẹni ma sọ pe awọn n mura fun eto idibo kankan ni Naijiria lọdun 2023, ayafi ti idibo ba waye laarin awọn ẹya to wa lorileede Naijiria lati sọ boya awọn ṣi fẹẹ wa lara orileede naa bi awọn fẹẹ maa lọ lati da duro.
Awọn ẹya tọrọ yii kan ni Yoruba, Ibo, Ijaw ati Middle Belt.
Ninu ipade naa, nibi ti Akitoye to jẹ alaga ẹgbẹ naa ti ṣoju Yoruba ni Tony Nnadi ti ṣoju ẹya Ibo ati Ijaw, nigba ti Ọjọgbọn Yusuff Turaki ṣoju awọn eeyan agbegbe Midle Belt.
Akintoye ṣalaye pe ki ẹnikẹni ma ronu tabi maa gbaradi fun eto idibo kankan lai ṣe pe ipade ti wọn yoo ti dibo ‘a n lọ’ tabi ‘a fẹẹ duro’ yii ba waye,
Bẹẹ lo pe fun pe ki wọn wọgi le ofin ọdun 1999 ti Naijiria n lo bayii, eyi to ni o kun fun irẹjẹ, jibiti, imunilẹru, ti ko si jẹ ki awọn ẹya to ku ni ilọsiwaju.