Dada Ajikanje
“Ko wu mi ki n pariwo rara pe oni lọjọ ibi mi o, ṣugbọn ohun tawọn eeyan mi ṣe jọ mi loju, wọn fi ifẹ han, wọn kẹ mi bii ọba, wọn bu iyi nla fun mi bii eeyan atata, bẹẹ ni ko sohun meji ti mo fẹẹ sọ ju pe, ọpẹ ni fun Oluwa, to ṣe gbogbo eyi fun mi.”
Ọkan pataki ninu awọn agba oṣere orilẹ-ede yii, Alagba Dele Odule, lo ṣe bayii sọrọ, nigba ti ALAROYE pe e lowurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ti i ṣe ọjọọbi rẹ.
Dele Odule sọ bayii pe, “Ohun ti mo ni lọkan ni pe mo fẹẹ rọra wa ibi kan gba lọ, mi o fẹ ariwo kan rara nipa ọjọọbi mi, bo tilẹ jẹ pe mo mọ daadaa pe awọn eeyan maa ranti ṣaa pe oni lọjọọbi ọkunrin yii. Mo ti ji loru ganjọ lati dupẹ lọwọ Ọlorun to fun mi loore-ọfẹ lati maa bẹ, bẹẹ ni mo ti ni in lọkan pe ma a sọ fun awọn ọmọ pe ki wọn sọ fun ẹnikẹni to ba beere mi pe mi o si nile, ṣugbọn emi ro o ni o, niṣe lawọn ẹni bii ẹni, awọn eeyan bii eeyan ni ohun rere mi-in lọkan fun mi.
“Deede aago mẹfa aarọ yii, mo bẹrẹ si i gbọ iro ilu bata, to n dun, to n ro kikankikan, bẹẹ iru agbegbe ti mo n gbe nisinyii ni Ibadan, ko saaye fun iru nnkan bẹẹ rara, nitori ko jọ ibi ti mo k̀ọle si. Emi tiẹ n wo o pe awọn wo ni wọn n pariwo laduugbo, aṣe awọn ọmọ Baba Adebayọ Faleti atawọn ti Duro Ladiipọ, ni wọn ko ilu bata waa ka mi mọle.
“Iyalẹnu lo jẹ o, bẹẹ ni inu mi dun gidigidi, wọn jọ mi loju, wọn ṣe mi bii ọba. Awọn araadugbo paapaa ko binu, wọn ko wo o bii ẹni pe ẹni kan wa laduugbo to n fariwo di awọn lọwọ, niṣe lawọn naa fi idunnu nla han si mi. Mo dupẹ lọwọ awọn naa pẹlu, ki Ọlọrun tubọ fun gbogbo wa lẹmi-in ati alaafia lati fi ba ara wa gbe daadaa.”
Oṣere ọmọ ipinlẹ Ogun yii sọ pe nibi ti awọn onibata ti n palẹmọ ilu wọn lọwọ lẹyin ti wọn ṣẹyẹ nla foun tan lawọn onidundun naa tun yọ, tawọn naa tun da ilu bolẹ, nni faaji ba tun bẹrẹ lẹẹkan si i.
“Mo ni ọmọ mi daadaa kan, Bọlaji Aṣiwaju, lorukọ ẹ, oun naa lo ko awọn onidundun wa o, bawọn yẹn naa tun ṣe ṣariya nla fun mi niyẹn, afi bii ẹni pe gbogbo ẹ pata la ti ṣeto fun tẹlẹ, bẹẹ lemi ko mọ ohunkohun.”
Nigba ti gbajumọ oṣere yii yoo sọrọ lori ohun ti agba ti n gba lọwọ ẹ, o ni, ọpọ iwa ọmọde tabi igba ewe ti agba maa n gba ti eeyan ba ti dagba loun naa ti kọ silẹ patapata. Bẹẹ lo sọ pe oun ti ni ipinnu tuntun lati foriji gbogbo awọn to ṣẹ oun, yala nidii iṣẹ ere sinima, ninu ẹbi, laarin ọrẹ ati laduugbo paapaa.
“Gbogbo awọn eeyan ti wọn ti ṣẹ mi ri pata ni mo ti foriji bayii, yala laarin awa oṣere ati nibomi-in gbogbo. Bẹẹ lemi naa n tọrọ aforiji bayii ki awọn eeyan ti mo ṣẹ pata foriji mi, ninu awọn ta a jọ n ṣere sinima, ninu mọlẹbi, laarin ọrẹ ati laduugbo. Ki Ọlọrun foriji gbogbo wa.”
Ṣiwaju si i, o ni titi di asiko yii loun ṣi n lọ soko ere daadaa, ati pe lọjọ Aiku, Sannde, gan-an loun pada wale, nitori ọjọọbi oun to n waye loni-in.
Nigba to n gba awọn ọdọ nimọran, paapaa lori bi wọn ṣe tu jade lati fi ero wọn han lori awọn ẹṣọ agbofinro SARS, o ni bi wọn ṣe jade lati fẹhonu han daa, bo tilẹ jẹ pe awọn kan wa ti wọn fi iwa janduku ba eto ọhun jẹ mọ wọn lọwọ.
Alagba Dele Odule fidi ẹ mulẹ pe oun ti le ni ọgọta ọdun, bẹẹ loun ko niṣẹ meji ju sinima ti oun n ṣe yii, ti oun si tibẹ di gbajumọ nla nidii ẹ.
O ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹ sinima ti yatọ bayii, pẹlu bi ẹrọ ayelujara ṣe wọ ọ, sibẹ, iṣẹ naa n tẹ siwaju, bẹẹ awọn ti awọn n ṣe e paapaa ko duro, nitori ohun to daju ju lọ laye yii naa ni ayipada. O ni aye ko duro, bẹẹ lọmọ ẹda paapaa ko sun. Bi ayipada ṣe n de ba ohun gbogbo lawọn naa n ba a yi pẹlu.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn oṣere ẹgbẹ ẹ ti wọn ti ki i lọpọlọpọ lori ikanni ayelujara loriṣiiriṣi. O ni oun mọ ọn loore bi wọn ṣe ranti pe oni ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla yii, ni wọn bi oun. Bakan naa lo ki gbogbo awọn ololufẹ ẹ pata, iyẹn awọn COSMOS ni gbogbo ilẹ Yoruba, titi to fi de Kogi, Ibadan Film Circle, Ogun State Governance, Pen Pushing; Ogun State Indigene ati State of Ogun. O loun dupe gidigidi lọwọ wọn.