Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe pẹlu oniruuru igbesẹ akinkanju ti iṣejọba Aarẹ Bọla Tinubu n gbe bayii, ijọba tiwa-n-tiwa ti rẹsẹ walẹ lorileede Naijiria.
O ṣapejuwe Tinubu gẹgẹ bii adari ti iwa rẹ n jẹ ijọloju ati iyalẹnu fun gbogbo eeyan, o si ke si gbogbo awọn ti wọn ti ko owo jẹ lorileede yii lati bẹrẹ si i da a pada gẹgẹ bii ami ifẹ.
Ninu atẹjade kan ti Oluwoo fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibrahim, Kabiesi ṣalaye pe Tinubu bẹrẹ daradara nipasẹ awọn igbesẹ to n gbe lori awọn eto kọọkan bii yiyọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu, ọrọ nipa owo Naira tuntun atawọn nnkan miiran to jẹ pe awọn wọbia nikan ni wọn n jẹgbadun wọn lorileede yii.
O ni to ba jẹ pe oun ti wa nipo ọba lasiko iṣejọba buburu lorileede yii ni, boya wọn iba ti pa oun, nitori ko si ẹni to le pa ohun (voice) mọ agogo oun lẹnu.
Ọba Akanbi waa ke si awọn ọmọ orileede yii ti wọn n tiraka lati ni ọrọ (wealth) pe ki wọn ṣe e lọna to tọ, nitori ko si aaye fun iwa ibajẹ mọ.
O ni ki awọn ajijagbara ni iha Ila Oorun Guusu ati Iwọ Oorun Guusu lorileede yii para pọ, ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ijọba to wa lode fun ọjọ ọla awọn ọmọ wọn, nitori asiko iditẹgbajọba ti lọ patapata, ijọba dẹmokresi la wa bayii.
Bakan naa lo fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe labẹ iṣakoso Aarẹ ti ki i fi iṣẹ ṣere ti a wa bayii, erejẹ ijọba tiwa-n-tiwa yoo pọ yanturu.
Bakan naa lọba alaye yii ke si ijọba lati gbe eto iranwọ kalẹ fun awọn araalu lori ọrọ ilera ati ilegbee.