Faith Adebọla, Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti kilọ fawọn eeyan ipinlẹ naa pe ki wọn ma ṣe wọ mọto BRT ti ko ba ti si ina ninu rẹ lalẹ.
O sọrọ naa lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Mobọlaji Johnson Arena to wa ni Onikan, niluu Eko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lasiko ayajọ awọn obinrin to waye.
Sanwo-Olu ni nigbakigba ti dẹrẹba BRT ba pa ina mọto rẹ, ohun to tumọ si ni pe o ti pari iṣẹ, o si n gbe bọọsi pada sibi ti wọn n wa a gunlẹ si.
O ni ti awọn eeyan ba ri bọọsi ti ko tanna lalẹ, ti ko si si ami to maa n fi bi mọto ṣe n rin tabi to n sare to maa n han nibi mọto naa han, ki wọn ma ṣe wọ ọ.
O ni bi gbogbo nnkan wọnyi ko ba ti si nibẹ mọ, kọndọkitọ yoo ti bọ silẹ ninu mọto ọhun, ofurugbada ni yoo si wa, ayafi dẹrẹba nikan to n lọọ paaki ọkọ sibi ti wọn n gbe e si nikan ni yoo wa ninu rẹ.
Ikilọ yii waye lẹyin ti wọn ri oku ọmọbinrin kan, Bamise Ayanlọwọ, to wọn mọto BRT, to si dawati, ki wọn too pada ri oku rẹ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Bakan naa lo ṣeleri pe gbogbo ohun to ṣokunkun nipa iku ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun naa lawọn yoo tu jade patapata. Bẹẹ ni ijiya to tọ yoo wa fun ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iwa buruku naa gẹgẹ bo ṣe sọ.
O fi kun un pe gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un lati ri i pe wọn ba ẹjọ naa debi to lapẹẹrẹ.