Faith Adebọla
Ọkan ninu awọn agbẹjọro ti yoo ṣaaju igbẹjọ Sunday Adeyẹmọ to n jijangbara fun Yoruba nni, Ọmọwe Malik Oluṣẹgun Falọla, ti fi da awọn eeyan loju pe awọn ọmọ Yoruba yoo foju kan Sunday laipẹ yii.
Malik sọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifiṣan ori ẹrọ ayelujara to wa niluu oyinbo, Heritage tẹlifiṣan ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Nigba to n ṣalaye ipa to ti sa lori ọrọ Sunday Igboho, ọkunrin naa sọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja ni oun kuro ni orileede France, ni nnkan bii aago meji Ọjọbọ, Tọsidee, toun ti n ṣiṣẹ agbẹjọro, oun si balẹ si ilẹ Benin ni nnkan bii aago mejila ọjọ Ẹti, Furaidee.
Falọla ni nitori awọn iwe oriṣiiriṣii ti wọn ni ki oun lọọ mu wa ki oun too le ri lo jẹ ki oun pẹ. Eyi ni wọn fi ni ki oun pada wa ni ọjọ Abamẹta, Satide.
Agbẹjọro yii ni oun lọ si ọdọ Igboho laaarọ ọjọ Abamẹta, oun si ri Igboho, ṣugbọn niṣe ni wọn so ṣeeni mọ ọn lọwọ siwaju. Ọkunrin yii ni ipo ti oun ba a yii ko dun mọ oun ninu, o ni oun sọ fun wọn pe o lodi sofin lati so o lọwọ si iwaju bi wọn ti ṣe e. Awọn eeyan naa ni ki i ṣe pe ẹnikẹni lo ni ki awọn so o lọwọ, ṣugbọn ẹru n ba awọn, ko maa baa sa lọ, ko si di wahala si awọn lọrun lawọn fi so o bẹẹ.
Agbẹjọro Fawọle ni oju ẹsẹ loun bẹrẹ si i pe awọn adajọ kan nibẹ pe ko tọna labẹ ofin bi wọn ṣe so o lọwọ.
Agbẹjọro yii ni ki oun too pada de, wọn ti yọ panpẹ ti wọn ko si i lọwọ.
Nigba ti wọn n beere lọwọ agbẹjọro yii pe ṣe alaafia ni Igboho wa, o ni ko si ohun to ṣe e. Ta a ba ti yọwọ ara riro, ori fifọ, atawọn nnkan pẹẹpẹẹ pẹẹ bẹẹ, ko si ohun to ṣe e. O fi kun un pe awọn ti gba dokita, wọn ti ṣayẹwo fun un, bẹẹ ni wọn ti fun un ni itọju to yẹ. Awọn si ti gba iwe lọdọ awọn dokita, gbogbo awọn iwe yii lawọn maa ko lọ sile-ẹjọ gẹgẹ bii ẹri lati pe ki awọn adajọ tu u silẹ.
Lara ipa ti ọkunrin naa ni oun tun sa ni pe oun ri i pe iyawo rẹ ni anfaani lati ri i, ko si maa gbe ounjẹ wa fun un. O sọ pe wọn ko fun un ni anfaani yii tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti oun ba awọn tọrọ kan sọrọ, wọn ti fun iyawo rẹ ni anfaani lati maa ri i, ko si maa gbe ounjẹ wa fun un, ko si maa waa wo o lẹẹmẹta lojumọ.
O ni pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe n lọ, awọn eeyan maa ri Sunday Igboho laipẹ yii.