Faith Adebọla, Eko
Ọkan-o-jọkan epe ati ọrọ buruku lawọn eeyan fi n ranṣẹ sawọn afurasi gende marun-un kan ti wọn fẹsun kan pe wọn fipa ba ọmọ ọdun mọkanla torukọ rẹ n jẹ Favour Okechukwu laṣepọ titi tọmọ naa fi dakẹ sabẹ wọn.
Irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye lagbegbe Ejigbo, nipinlẹ Eko.
Ninu ọrọ ti Amofin Helen Ibeji to jẹ Aarẹ ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ awọn obinrin atawọn ọmọde kan (International Charitable Initiative for Girl Child and Woman Development Foundation), ba AKEDE AGBAYE sọ lori foonu lori iṣẹlẹ ọhun, o ni Ojule kẹrin, Opopona Ọlanrewaju, l’Ejigbo, lọmọ naa n gbe pẹlu awọn obi rẹ. Mama Flavour lo ran an niṣẹ nirọlẹ ọjọ naa pe ko lọọ ba oun ra paali Indomie kan wa, ọmọ naa si maa gba adugbo kan ti wọn n pe ni Powerline kọja. Adugbo Powerline yii ni wọn lawọn eeyan kan kọ ile kẹbujẹ atawọn onipako si loriṣiiriṣii, labẹ waya ina ẹlẹntiriiki to kọja lagbegbe ọhun, awọn ọmọ ganfe si maa n wọpọ lawọn ibẹ.
O to ki Favour de, ko de, lawọn obi rẹ atawọn alajọgbele wọn ba bẹrẹ si i wa a gba gbogbo ọna ti wọn ro pe o ṣee ṣe ko gba kọja lọ. Wọn ni bo ṣe ku diẹ ki wọn de adugbo Powerline yii ni wọn pade ọkunrin kan to porukọ ara ẹ ni Tabi, ṣugbọn inagijẹ tawọn eeyan n pe e ni T-boy, ọmọ ipinlẹ Cross-River ni. Ọkunrin naa lo sọ fun wọn pe agọ ọlọpaa loun n lọ yii tori boun ṣe dari wọle lati ibiiṣẹ loun ri i pe wọn ti ja ilẹkun yara oun, ṣiṣi silẹ loun ba ilẹkun ile pako toun n gbe.
Wọn lọkunrin naa ni boun ṣe wọle loun ba oku ọmọbinrin kekere kan ninu yara naa, ihooho goloto lọmọ ohun wa, bata ati aṣọ rẹ ti wa lọtọọtọ, ati pe gbogbo inu ile naa lo ri wuruwuru yatọ si boun ṣe fi i si nigba toun n lọ sibiiṣẹ laaarọ ọjọ iṣẹlẹ ọhun.
Bawọn eeyan ṣe tẹle T-boy ree, iyalẹnu ati ibanujẹ nla lo si jẹ nigba ti wọn yẹ oku naa wo, ti wọn ri i pe Favour Okechukwu lawọn kọlọransi ẹda kan ti ṣe baṣubaṣu titi doju iku.
Ẹnikan ti wọn ko darukọ rẹ ni wọn lo sọ fawọn ọlọpaa teṣan Ejigbo to wa sibi iṣẹlẹ ọhun pe oun ri awọn gende marun-un ti wọn sare jannajanna jade laipẹ si asiko naa, ṣugbọn ọọkan loun ti ri wọn, oun o mọ ohun to ṣẹlẹ, ṣugbọn ọgangan ile T-Boy ni wọn ti tu jade.
Ṣa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Olumuyiwa Adejọbi, lawọn ti fi pampẹ ofin gbe Ọgbẹni Tobi to ni yara tọmọ ku si, awọn si ti ri awọn mẹrin mi-in mu ti wọn fura si lori iṣẹlẹ yii, o lawọn ti taari gbogbo wọn si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, fun iṣẹ iwadii.
Alaga ijọba ibilẹ Ejigbo, Ọnarebu Mudashiru Obe ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, o si ṣeleri pe oun yoo gba iyọnda ijọba lati wo gbogbo awọn ile pako to wa labẹ waya ina ọhun laipẹ, tori ibi ti ijọba ko fọwọ si ni wọn kọle naa si, ati pe awọn ọmọ ganfe ti sọ awọn ile pako naa di ibi iwa ọdaran ati ifipabanilopọ lagbegbe ọhun.
Ọnarebu Obe tun sọ pe awọn maa bẹrẹ si i lo awọn ẹṣọ alaabo fijilante lati maa ṣọ gbogbo ibi ti wọn ba fura pe awọn janduku ẹda fẹẹ maa fori pamọ si nijọba ibilẹ naa.
CAPTION