Faith Adebọla
Bawọn eeyan ṣe n ṣepe fun ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji yii, Ọgbẹni Danasabe Eddo, bẹẹ lawọn mi-in n bu u ni mẹsan-an mẹwaa, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe niṣe lo wọle lọọ ba iya arugbo ẹni ọgọrin ọdun kan to n da gbe, lo ba ki mama naa mọlẹ, o si fipa ba a laṣepọ.
Iṣẹlẹ yii, bawọn ọlọpaa ṣe sọ ninu atẹjade kan ti Ramhan Nansel, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, fi lede lọjọ Aiku, Sannde yii, waye labule Kundami, niluu Garuku, ijọba ibilẹ Kokona, nipinlẹ ọhun.
Wọn ni ọmọ bibi ipinlẹ Kaduna lọkunrin to huwa ọdaran yii, ṣugbọn abule kan naa loun ati mama arugbo naa n gbe.
Awọn ọlọpaa ni ipe idagiri kan lawọn gba lori aago nipa iṣẹlẹ ọhun, nigba tawọn agbofinro si de’bẹ, wọn ba mama arugbo naa nibi ti ọkunrin yii ṣe e yankan yankan si, o ti fipa ba a laṣepọ, nigba tawọn eeyan abule naa ko si nitosi, lo ba sa lọ.
Lẹyin ti wọn fimu finlẹ, wọn ri afurasi ọdaran naa nibi to lọọ sa pamọ si ninu igbo, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e, wọn si gbe mama to ba sun lọ sileewosan fun itọju.
Wọn lọkunrin naa sọ ni teṣan ọlọpaa pe iṣẹ eṣu ni, ki wọn ṣaanu oun.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, CP Adeṣina Ṣoyẹmi ti paṣẹ ki wọn taari Eddo si awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to n tọpinpin iwa ọdaran abẹle, o ni ọdọ wọn lo maa gba dewaju adajọ laipẹ, o si gba awọn araalu lamọran lati maa ṣọ awọn arugbo wọn, ki wọn si maa daabo bo wọn lọwọ awọn kọlọransi ẹda to le fẹẹ ko wọn nifa.