Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọmọbinrin kan ti ara rẹ ko da pe pade agbako ibasun lanaa ode yii ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun. Bo ti jẹ abirun to, ko di Godwin Akpan, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to fipa ba a lo pọ lọwọ.
Gẹgẹ bi ẹgbọn ọmọ ti Godwin ba sun ṣe wi, o ni Sango lawọn n gbe, geeti ile awọn loun si ni kọmọ naa lọọ ti ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ naa, bi Godwin tawọn jọ n gbe nibi kan naa ṣe fa ọmọbinrin ẹni ogun ọdun ti ara rẹ ko da pe naa wọle niyẹn, o si fipa ba a laṣepọ karakara.
Akpan funra ẹ jẹwọ lẹyin tọwọ ba a tan, o ni lootọ loun ki abirun ọmọge naa mọlẹ, ṣugbọn oun ko mọ ohun to ko soun lori toun fi ṣe e, o loun ti gbe nnkan si i lara tan koun too mọ pe ko daa.