Gomina Abdurazaq bura fawọn kọmisanna tuntun ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjila, ọdun 2022, ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq,  bura wọle fun awọn kọmisanna tuntun meji Sa’adatu Modibbo-Kawu ati Abubakar  Buhari,.

Abdurazaq tun Modibbo-Kawu yan gẹgẹ bii kọmiṣanna lẹka eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, nigba to yan Buhari gẹgẹ bii kọmiṣanna lẹka ibanisọrọ. Bakan naa lo tun bura wọle fun Alaaji Abdul-Razhaq Jiddah, gẹgẹ bii oludamọran pataki lori awọn ojuṣe pataki.

Abdurazaq tun mu atunto ba awọn kọmiṣanna marun-un miiran: Alaaji Wahab Agbaje lati ọfiisi to n ri si ọrọ omi lọ si ọfiisi to n ri si ohun amusagbara, Mariam Hassana, lati ọfiisi ohun amusagbara lọ si eyi to n ri si ọrọ awọn obinrin.

Awọn miiran ni Abdulmaliq Risikatulahi, lati eyi to n ri si ọrọ obinrin si ti ọrọ omi. George Towoju, lati ẹka ibanisọrọ lọ si ẹka to n ri si idagbasoke awọn ọdọ ati Adamu Jamila, lati kọmiṣanna to n ri si ọrọ idagbasoke awọn ọdọ si kọmiṣanna to n ri si eto abo.

Gomina rọ gbogbo wọn ki wọn fi ọkan atara sin awọn eniyan wọn, ki wọn si fọwọsowọpọ  pẹlu ijọba to wa lode, ki wọn le ṣe aseyege ati aṣeyọri.

Leave a Reply