Gomina Adeleke tu igbimọ alaṣẹ Fasiti Ọṣun ka

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinle Osun, Sẹnetọ Nurudeen Ademọla Adeleke, ti kede titu awon ọmọ igbimọ to n ṣakoso Fasiti Ọṣun ka.

Lasiko Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsọla gẹgẹ bii gomina ipinlẹ ọhun ni won yan awon igbimọ ti Agbẹjọro Agba, Yusuf Alli, jẹ alaga fun ọhun lọdun 2006.

Lẹyin ti wọn pari saa akọkọ ọlọdun marun-un ni gomina ana, Alhaji Gboyega Oyetọla, tun tun wọn yan lati lo saa miiran.

Ṣugbọn ninu atejade kan ti Olori awon oṣiṣẹ ọba nipinlẹ Ọṣun, S. A. Aina, fi sita lo ti sọ pe gomina dupẹ lọwọ awọn igbimọ naa fun ifara-ẹni-jin wọn fun idagbasoke UNIOSUN.

O gbadura pe ki Ọlọrun tubọ mu wọn ṣaṣeyọri ninu gbogbo idawọle wọn.

 

Leave a Reply