Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gbogbo eto lo ti to bayii lati fi Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, jẹ Aṣiwaju ilu Ẹdẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un ọdun yii.
Ifijoye yii lo ṣe wẹku pẹlu ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹrinlelọgọta ti Adeleke dele aye.
Gẹgẹ bi alaga ayẹyẹ onibeji naa to jẹ aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ọṣun nileegbimọ aṣofin agba, Akọgun (Dokita) Lere Oyewumi, ṣe wi, aafin Timi, Ọba (Dr) Munirudeen Adeṣọla Lawal, ni ayẹyẹ naa yoo ti waye.
Lara awọn eeyan pataki ti wọn n reti nibẹ ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Alhaji Aliko Dangote ti yoo jẹ alaga, Oloye Victoria Adunọla Samson (Mama Bovas), Arabinrin Fọlọrunsọ Alakija.
Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ni yoo ko awọn ori-ade sodi, nigba ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, yoo gba awọn gomina to n bọ kaakiri orileede yii lalejo.
Nibi eto naa, Akọgun Oyewumi sọ pe wọn yoo ṣe ifilọlẹ aafin igbalode ẹlẹgbẹlẹgbẹ biliọnu Naira fun Timi Ẹdẹ, Dokita Deji Adeleke ni yoo si jẹ olugbalejo ọjọ naa.
Tẹ o ba gbagbe, ẹgbọn gomina, Oloogbe (Sẹnetọ) Isiaka Adetunji Adeleke, ni Aṣiwaju akọkọ fun ilu Ẹdẹ.
Oṣu kin-in-ni, ọdun 1994, ni Timi ilu Ẹdẹ nigba naa, Ọba Tijani Ọladokun Oyewusi (CON), Agbọnran Keji, jawe oye Aṣiwaju ilu naa le Sẹnetọ Isiaka Adeleke lori.
Adeleke, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Ṣẹrubawọn, lo ipo naa fun idagbasoke ilu Ẹdẹ titi digba to doloogbe lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2017.
Latigba naa ni ipo Aṣiwaju ilu Ẹdẹ ti ṣi silẹ, ko too di pe awọn igbimọ Timi pinnu lati fi Gomina Ademọla Adeleke jẹ oye naa bayii.