Gomina Ademọla Adeleke dibo l’Ọṣun, o gboṣuba funjọba Buhari

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ni deede aago mẹsan-an ku iṣẹju mẹrindinlogun ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, dibo nileedibo kẹsan-an, Wọọdu 2, ni Ṣagba/Abogunde, niluu Ẹdẹ.

Nigba to n sọrọ lẹyin to dibo tan, o ba awọn eeyan agbegbe to ti dibo naa sọrọ. Gomina Adeleke gboriyin fun ijọba Buhari fun igboya ati ipinnu to ni lati ṣe ofin eto idibo tuntun ti wọn n pe ni Electoral law.

Bakan naa lo rọ awọn araalu lati jade lọpo yanturu ki wọn waa dibo, ki ẹnikẹni ma si ṣe fa wahala kankan.

 

Leave a Reply