Aderohunmu Kazeem
Ẹbẹ ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Enjinnia Ṣeyi Makinde, n bẹ awọn ọlọpaa bayii pe ki wọn tete pada sẹnu iṣẹ wọn lati koju iwa ọdaran to le maa ṣẹlẹ niluu, niwọn igba ti ko ba ti si ẹṣọ agbofinro kankan to le yẹ awọn ọdaran lọwọ wo.
Nibi ipade ti gomina yii ba awọn lọgaalọgaa lẹnu iṣẹ ọlọpaa, ṣe ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Ẹlẹyẹle, niluu Ibadan, lo ti sọrọ ọhun.
Gomina yii ti fi awọn ọlọpaa lọkan balẹ pe oun yoo ṣiṣẹ lori gbogbo ibeere ati awọn ohun amayedẹrun wọn ti kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa beere fun, ki igbe aye irọrun le wa fun wọn.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti ṣẹleri pe awọn ọlọpaa ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko rogbodiyan SARS naa yoo janfaani ninu ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira tijọba ti pese silẹ fun gbogbo awọn ti wọn faragba ninu iṣẹlẹ ọhun.
O ni, “Mo ba yin kẹdun awọn eeyan yin ti ẹ padanu ninu iṣẹlẹ ọhun, loootọ ni mo sọ pe mo fara mọ iwọde awọn ọdọ, ṣugbọn eyi ko sọ pe mo kọyin si ẹyin ọlọpaa rara. Ati pe ọrọ ẹyin ọlọpaa paapaa wa ninu koko marun-un ti awọn ọdọ to ṣewọde yii n beere fun. Igbe aye irọrun fun ẹyin naa jẹ wọn logun. Ohun ti a nilo bayii ni lati ṣiṣẹ papọ pẹlu araalu, ki igbagbọ wọn ninu yin si duro ṣinṣin.”
Makinde, fi kun un pe oun ti ri iwe ti kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa fi sọwọ soun, ijọba ipinlẹ Ọyọ si ti ṣetan lati ṣiṣẹ lori awọn ibeere ọhun.
O ni gbogbo teṣan ọlọpaa ti wọn sọna si ni ijọba yoo tunṣe, bẹẹ lawọn mọlẹbi ọlọpaa to ku paapaa yoo ri ohun idunnu latọdọ ijọba.
Ọlọpaa marun-un ni wọn pa nipinlẹ Ọyọ, nigba ti mejila ninu wọn fara pa, ti teṣan ọlọpaa marun-un naa si fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun.