Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Jẹnẹra Adetunji Olurin to ti figba kan ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ laye ijọba ologun ti ku o.
Aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, ni ọkunrin ọmọ bibi ilu Ilaro naa jade laye lẹni ọdun mẹrindinlọgọrin (76). A gbọ pe ọsibitu ijọba, LASUTH, to wa nipinlẹ Eko, ni oloṣelu naa dakẹ si.
Ọjọ kẹta, oṣu kejila, ọdun 1944, ni wọn bi Adetunji Olurin. Oloogbe dije dupo gomina ipinlẹ Ogun ninu ẹgbẹ PDP lọdun 2011. Oun ati Gboyega Nasir Isiaka ni wọn jọ n fa kinni ọhun mọra wọn lọwọ nigba naa. Oloye Ọbasanjọ wa lẹyin Olurin, nigba ti Gbenga Daniel n fi atilẹyin tiẹ han fun GNI, Gboyega Nasir Isiaka.
Nigba ti GNI deede gba ẹgbẹ tuntun lọ, iyẹn PPN, Olurin dije labẹ PDP, ṣugbọn ipo gomina Ogun ko bọ si i lọwọ, Ibikunle Amosun lo pada di gomina lọdun naa.
Nigba to di ọjọ kọkandinlogun, ọsu kẹwaa, ọdun 2006, Oloye Ọbasanjọ yan Adetunji Olurin gẹgẹ bii alakooso ipinlẹ Ekiti, o fi i rọpo Ayọdele Fayoṣe ti ijọba apapọ, labẹ Ọbasanjọ, yọ danu, pe o ṣe owo Ekiti mọkumọku.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2007, ni Jẹnẹra Adetunji Olurin fi ipo alakooso ipinlẹ Ekiti silẹ, Adetọpẹ Ademiluyi lo gbapo naa lọwọ rẹ nigba yẹn.
Oloogbe ti sinmi ninu oṣelu tojọ mẹta, ko too di pe ọlọjọ waa de yii. Ọdun 1975 lo fẹ iyawo rẹ, Kẹhinde Oyelẹyẹ, wọn si bimọ ọkunrin meji