Gbogbo awọn ti wọn gbọ ọrọ ti Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, sọ pe ki ijọba gbe ofin dide ti yoo fopin si bi awọn Fulani darandaran ṣe n daran lati Oke-Ọya wa si awọn ilẹ apa Ariwa lo n kan saara si i.
Lasiko tawọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC mẹwaa kan ṣepade pẹlu Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, niluu Daura, nipinlẹ Katsina, nibi to ti n lo isinmi ọlọjọ mẹrin to lọ fun ni Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, ti pe fun ofin ti yoo fofin de bi awọn Fulani ṣe n da ẹran wa si ilẹ Yoruba lati Oke-Ọya.
Gomina naa ni bi opin ko ba de ba eleyii, ija to n fojoojumọ ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ atawọn darandaran ko ni i dopin.
Ganduje ni oun ti n kọ ibujẹ ẹran sinu igbo kan ti wọn n pe ni Samsosua, ni aala ipinlẹ Kano si Katsina. O ni awọn ti le awọn janduku kuro ninu igbo yii.
O fi kun un pe ibujẹ ẹran yii yoo ni ile ti wọn yoo maa gbe, odo ti wọn yoo ti maa mu omi, ibudo ibi ti wọn yoo si ti maa gbe awọn ẹran wọn gun ati ọsibitu ti wọn yoo ti maa tọju awọn ohun ọsin wọn yoo wa nibẹ.
Gomina Kano ni awọn fẹẹ fopin si ki wọn maa da ẹran lati Oke-Ọya wa si awọn apa isalẹ ni ilẹ Yoruba.
Nidii eyi, ofin gbọdọ wa ti yoo fofin de wọn, nitori bi igbesẹ yii ko ba waye, ija ojoojumọ to n ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ atawọn darandaran ko ni i dopin.