Gomina Matawalle lulẹ ni Zamfara, Lawal lo wọle

 

Faith Adebọla

Erongba Gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle, lati lọ fun saa keji lori aleefa ti fori ṣanpọn, pẹlu bi wọn ṣe kede pe oludije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Ọgbẹni Dauda Lawal, lo jawe olubori.

Lawal gbẹyẹ lọwọ Matawalle pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna ọrinlelọọọdunrun din mẹta (377,726) eyi to fi nnkan bii ẹgbẹrun mẹrindinlaaadọrin ibo tayọ ti Matawalle to n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ibo ọọdunrun le mọkanla (311,976) loun ni.

Nigba to n kede ijawe olubori Lawal, adari eto idibo naa, Ọjọgbọn Kassimu Shehu, sọ lafẹmọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta yii, pe: “Emi, Ọjọgbọn Kassimu Shehu, lati Federal University Birnin Kebbi, nipinlẹ Kebbi, ni mo jẹ alakooso eto idibo sipo gomina to waye nipinlẹ Zamfara.

“Mo kede pe Dokita Lawal Dauda, ti ẹgbẹ oṣelu PDP, kunju oṣuwọn gbogbo ohun ofin beere fun, oun lo si ni ibo to pọ ju lọ, tori ẹ, oun lo gbegba oroke, mo si kede rẹ gẹgẹ bii gomina ta a ṣẹṣẹ dibo yan fun ipinlẹ Zamfara.”

E o ranti pe ọpọ awuyewuye lo ti waye lori eto idibo sipo gomina nipinlẹ naa. Owurọ ọjọ Aje, Mọnde, lawọn agbebọn kan lọọ rẹbuu awọn oṣiṣẹ ajọ INEC ti wọn n ko esi idibo lati ijọba ibilẹ Maradun lọ si Gussau, nibi ti wọn ti maa ṣe akojọ ati aropọ ẹ, ti wọn si ji wọn gbe.

Ẹ o tun ranti pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lo wọle ibo sipo gomina nipinlẹ ọhun lọdun 2019, amọ nitori ariyanjiyan ati ẹjọ to wa ni kootu lori eto idibo abẹle ẹgbẹ wọn, ile-ẹjọ to ga ju lọ dajọ lọjọ kẹrinlelogun oṣu Karun-un ọdun 2019, iyẹn ọsẹ kan si asiko ti wọn yoo ṣe ibura-wọle fun gomina, pe eto idibo abẹle naa ko bofinmu, tori ẹ, wọn yẹ aga nidii gomina adiboyan tuntun ọhun, Ọgbẹni Muktar Idris, wọn ni ki INEC gbe ẹgbẹ oṣelu ti ibo rẹ ba tun pọ tẹle ti APC wọle, eyi lo si ṣilẹkun fun Bello Matawalle, ti ẹgbẹ oṣelu PDP nigba yẹn, lati di gomina.

Amọ leyi ti ko ju ọdun meji lẹyin igba naa, Gomina Matawalle, atawọn aṣofin ipinlẹ kan pin gaari pẹlu ẹgbẹ PDP to gbe e sipo, o bọ si ẹgbẹ APC. Latigba naa si lawuyewuye ti n lọ laarin ẹgbẹ mejeeji nipinlẹ ọhun. Awọn kan tilẹ wọ ọ lọ ile-ẹjọ nitori ẹ, amọ kootu ko da wọn lare, wọn ni ẹgbẹ to ba wu gomina lo le bọ si, pe ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ.

Leave a Reply