Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣeto pinpin irẹsi ọdun fun awọn araalu.
Bakan naa lo fọwọ si sisan owo oṣu kejila fawọn oṣiṣẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, lati le ri nnkan fi ṣe ọdun Keresimesi.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe ijọba, Alhaji Teslim Igbalaye, fi sita, ogoji irẹsi ni yoo lọ si wọọdu kọọkan kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
Lati le ri i pe ko si iyanjẹ, ẹlẹyamẹya tabi ẹlẹsinjẹsin ninu pipin irẹsi naa, wọn gbe igbimọ kalẹ lati ṣakoso rẹ. Lara awọn igbimọ naa ni aṣoju ẹgbẹ awọn Musulumi kan, aṣoju ẹgbẹ Onigbagbọ kan, aṣoju ẹgbẹ ẹlẹsin abalaye kan.
Awọn to ku ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan ni wọọdu naa, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan, aṣoju kan latọdọ awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ati aṣoju awọn obinrin kan.
Igbalaye ṣalaye pe latọdọ Ẹgbẹ Olowo nipinlẹ Ọṣun nijọba ti ra irẹsi naa ni ẹgbẹrun mejilelọgbọn Naira.
Loni-in kan naa, Agbẹnusọ fun gomina, Mallam Rasheed Ọlawale, sọ pe Gomina Adeleke ti dun awọn oṣiṣẹ ijọba kaakiri ipinlẹ Ọṣun ninu nipa fifi ọwọ si sisan owo-oṣu wọn.
O ni wọn yoo bẹrẹ si i gba alaati owo wọn lati le ri nnkan fi ṣe ọdun nitori igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ ijọba wa lara koko marun-un ileri ti oun ṣe fun wọn lasiko ipolongo ibo.