Jọkẹ Amọri
Awọn ẹgbẹ kan ti wọn pera wọn ni ‘Grassroots 37 fun Ọṣinbajo’, ti rọ Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lati jade, ko si dije dupo aarẹ ilẹ wa ninu eto idibo ọdun to n bọ.
Ki i ṣe ẹnu lasan ni wọn fi sọrọ naa, wọn tun da ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹ gbẹta Naira (500,000) jọ, wọn lawọn fi ṣe iranlọwọ fun un ninu owo ti yoo fi gba fọọmu.
Alaga wọn, Ajihinrere Kọlade Ṣẹgun-Ọkẹowo lo fọrọ naa lede niluu Eko. Ninu lẹta kan ti wọn kọ si Igbakeji Aarẹ ni wọn ti rọ ọ ko waa dije, ti wọn si fi lẹta naa le aṣoju Ọṣinbajo, Dapọ Akinọṣun (SAN), lọwọ pẹlu iwe sọwedowo ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ti wọn ni awọn fi ṣe iranlọwọlara owo ti yoo fi gba fọọmu nigbakugba ti ọkunrin naa ba jade.
Ọkẹowo ni ẹbun ti awọn mu wa yii jẹ ami atilẹyin awọn ati erongba ọpọlọpọ ọmọ Naijiria fun pe ki Ọṣinbajo jade lati dupo aarẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, Akinọṣun dupẹ lọwọ awọn eeyan naa fun igbesẹ iwuri ti wọn gbe naa. O fi kun un pe Igbakeji Aarẹ ni gbogbo ohun to pe fun lati ṣe olori orileede yii. Bakan naa lo sọ pe oun paapaa ṣetan lati ṣatilẹyin fun igbesẹ naa.
Ọkunrin naa ni ayipada ti ko lẹgbẹ ni yoo ba orileede Nijiria ti Ọṣinbajo ba fi le di aarẹ ilẹ wa.O fi kun un pe awọn ko ni i yee rọ ọ lati jade dupo aarẹ naa titi ti yoo fi gbọ si awọn lẹnu.