Ajalu ti di meji fun wọn ni ipinle Edo bayii o. Wọn ti ji iyawo ati ọmo olori ile-igbimọ aṣofin ibe tẹle, Zakawanu Garuba, gbe lọ. Abuja ni wọn ti n bọ, Binni ni wọn n lọ, nigba tawọn ajinigbe naa da wọn lọna loju ọna Lọkọja si Abuja, ni ipinle Kogi. Ni wọn ba ji iya ati ọmọ naa gbe lọ. Ohun to mu ajalu naa pe meji ni pe olori ile-igbimọ aṣofin tẹlẹ naa sẹṣe ku laaarọ oni yii ni, nigba ti iya ati ọmo si n lọ sibi oku baba wọn yii ni wọn ji wọn gbe.
Abuja ni iyawo yii ati ọmo rẹ wa, pẹlu iya wọn agba, ọrọ iku naa lo si jẹ ki gbogbo wọn gbera lẹsẹkẹsẹ ti wọn gbọ, ki wọn le tete dele lati lọọ wo oku baba wọn. Nibẹ lawọn ajinigbe naa ti kọ lu wọn nitosi Okene, ti wọn si gbe iya ati ọmọ wọ inu igbo lọ. Wọn fi dẹrẹba silẹ, bẹẹ ni wọn fi iyaagba naa silẹ, iyawo olori awọn aṣofin naa pelu ọmo rẹ ni wọn gbe.
Ọga ọlọpaa pata fun ipinlẹ Kogi, Ayuba Ede, ni oun ti gbọ ọrọ naa, oun si ti da awọn ọmọ oun sita, ki wọn le le awọn ọdaran naa ba, ki wọn too rin jinna sigboro.
Gomina Gaius Obaseki ṣii n daro iku to pa agba oloṣelu adugbo wọn yii lọwọ ni o, afi bi ti iyawo rẹ ati ọmọ ṣe tun yi lu u yii, ko si si ohun meji ti awọn eeyan n sọ nile ijọba Ẹdo bayii ju, ‘Iru ajalu wo wa leyi!’ lọ.