Adewale Adeoye
Mẹta lara awọn ọmọ orileede Nigeria kan ti wọn n gbe lagbegbe Phuket, lorileede Thailand, lọwọ awọn agbofinro orileede naa ti tẹ bayii, o si ṣee ṣe ki wọn fi wọn jofin laipẹ yii lori iwa ọdaran ti wọn mu wọn fun ọhun.
Awọn mẹta ọhun ni: Ogbẹni Solomon, ẹni ọdun mẹtalelaaadọta, Ọgbẹni Harrison ati Ọgbẹni Ogadinma.
ALAROYE gbọ pe ọmọ orileede Russia kan, Ọgbẹni Denis, ni awọn araalu naa lọọ fọrọ rẹ to awọn alaṣẹ ijọba orileede naa leti lori ẹsun pe o n ṣowo egboogi oloro laarin ilu Phuket, lorileede Thailand. N lawọn ọlọpaa agbegbe naa ba ṣe bii onibaara rẹ, wọn lọọ ra egbogi oloro kokeeni lọwọ rẹ, owo nla lo si ta a fun wọn, loju-ẹsẹ ti wọn ra ọja ofin naa lọwọ rẹ tan ni wọn ti fi ọwọ ofin mu un. Wọn yẹ inu mọto jiipu rẹ wo, wọn ba ọpọlọpọ egboogi oloro nibẹ. Ọgbẹni Denis yii lo mu awọn ọlọpaa ọhun lọ sọdọ awọn ọmọ orileede Naijiria meji kan, Harrison ati Ogadinma, wọn ba egboogi oloro lọwọ awọn yẹn naa, ni wọn ba fọwọ ofin mu wọn ju sahaamọ wọn. Ki iya naa ma baa jẹ wọn gbe ni awọn naa ba tu aṣiri pe baba isalẹ awọn gan-an ni Solomon, awọn ọlọpaa lọ sọdọ rẹ, wọn ba obitibiti egboogi oloro lọwọ rẹ, ni wọn ba fọwọ ofin mu oun naa loju-ẹsẹ.
Ọga agba ẹṣọ to n ṣọ odi ilu Deputy Chief Immigration, Ọgbẹni Phanthana Nutchanart, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, sọ pe lati inu oṣu Kẹrin, ọdun yii, lawọn ti n dọdẹ awọn afurasi ọdaran ọhun ko too di pe ọwọ tẹ wọn loṣu yii.
O ni awọn n ṣewadii lọwọ nipa awọn afurasi ọdaran ọhun, tawọn si maa too foju gbogbo wọn pata bale-ẹjọ laipẹ yii.