Haa, Obi gbe Tinubu lulẹ l’Ekoo

Jọkẹ Amọri

Oludije ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu Labour, Ọgbẹni Peter Obi, ti fibo na Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ APC, nitori oun lo ni ibo to pọ ju lọ. Loootọ ni Tinubu ni ijọba ibilẹ mọkanla, Obi si ni mẹsan-an pere, ṣugbọn apapọ awọn ibo ti wọn di ni ibi ti ero pọ si ju lọ, Obi lo mu ibẹ, to si fi ibo naa na Tinubu.

Awọn ijọba ibilẹ nla nla bii Alimọṣọ, nibi ti Raufu Arẹgbẹsọla ti maa n paṣẹ tẹlẹ, Obi lo mu ibẹ, bẹẹ ni Amuwo Ọdọfin, ati Ikẹja paapaa. Ni apapọ, ibo ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta din mejidinlogun (582, 664) ni Peter Obi ni lapapọ, ti ti Tinubu si jẹ Ojilelẹẹẹdẹgbẹta ati ẹyọ kan (541, 850), eyi ni pe bii ẹgbẹrun lọna ogoji ibo ni Obi fi fi idi Aṣiwaju kalẹ, ọrọ naa si ya gbogbo ilu lẹnu.

Idi iyalẹnu yii ni pe nigba ti Tinubu wa lati ṣe kampeeni rẹ pari niluu Eko lọsẹ to kọja yii, awọn ero ti wọn jade ko jẹ ki onimọto tabi ẹlẹsẹ rin, ero naa papọju debii pe Aarẹ Muhammadu Buhari funra ẹ ko ribi gbẹsẹ si nigba to de. Bi Wasiu Ayinde si ti n kọrin ‘Ọmọ olodoodẹ, ọmọ oloodoode, bẹẹ lawọn ero naa n ho, ti wọn si n jo, ko si sẹni kan to nigbagbọ pe to ba di ọjọ idibo, awọn ero rẹpẹtẹ yii ko ni i jade dibo fun un.

Esi idibo yii ki i ṣe ohun ti yoo mu inu ẹnikẹni ninu awọn APC dun, nitori iṣoro gbaa ni fun ẹni to ba n dupo aarẹ ti ko le mu ipinlẹ to ti wa. Ipinlẹ mejeeji ti wọn n ki Aṣiwaju Tinubu mọ, iyẹn Eko ati Ọṣun, mejeeji naa lo bọ mọ ọn lọwọ bayii, ti ko si si ohun to le ṣe. Ti wọn ba n ka iye awọn ipinlẹ ti Aṣiwaju Tinubu ni bayii, ipinlẹ mejeeji yii ko ni i si nibẹ, eyi si le ṣakoba fun un nigba ti wọn ba fẹẹ ka iye ibo ipinlẹ lapapọ.

Ṣugbọn ọpọ ibo ṣi ku ni awọn ipinlẹ kaakiri, o si digba ti wọn ba ka kinni naa tan pata ka too mọ ẹni to ṣaaju ninu awọn oludije gbogbo.

Leave a Reply