Stephen Ajagbe, Ilorin
Adajọ Ọlaolu Muyiwa, tile-ẹjọ Magisreeti ilu Ilọrin ti ni ki wọn gbe afurasi kan, Habeeb Yusuf, lọ ṣahaamọ ọgba ẹwọn to wa l’Oke-Kura, niluu Ilọrin, fẹsun pe o ji ewurẹ gbe.
Ileeṣẹ ọlọpaa lo wọ Habeeb lọ sile-ẹjọ fẹsun ikọja-aaye lọna ti ko ba ofin mu ati ole.
Adajọ Muyiwa ni ki olujẹjọ naa ṣi wa lahaamọ titi tiwadii ileeṣẹ yoo fi pari lori ẹsun ti wọn fi kan an. O sun ẹjọ naa si ọjọ kejilelogun, oṣu kẹta, ọdun yii.
Akọsilẹ ọlọpaa ṣalaye pe ọwọ tẹ Habeeb laduugbo Adeta, niluu Ilọrin, lasiko to ji ewurẹ naa gbe, to si fẹẹ maa sa lọ.
Wọn ni awọn araadugbo lo mu un, ti wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ.
Ṣaaju ni agbẹjọro ijọba, Zacheaus Fọlọrunṣọ, ti rọ ile-ẹjọ lati ma gba oniduuro rẹ, ko lọọ wa latimọle.
Olujẹjọ ọhun loun ko jẹbi ẹsun naa lẹyin tile-ẹjọ ka a si i leti.