Jide Alabi
Ọmọọba Hakeem Ajasa, ọkan lara awọn ọmọọba niluu Iru, l’Ekoo, ti sọ pe Aṣiwaju Bọla Tinubu, ati Gomina Babajide Sanwo-Olu ni wọn da ọrọ oun ru, ti wọn ko jẹ ki oun di ọba ilu Iru, lẹyin tawọn eeyan oun ti yan oun fun ipo naa.
Bo ṣe n mura-silẹ lati lọ sile-ẹjọ bayii gan-an ni wọn lo mu Ọmọọba Ajasa latinu ẹbi Abisogun kọ lẹta ohun to fẹẹ tori ẹ pe wọn lẹjọ si ijọba Eko atawọn mi-in ti ọrọ kan, paapaa Bọla Tinubu, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ijọba ibilẹ Eti-Ọsa, adajọ agba nipinlẹ Eko, Ọba Ikate Elegushi, kọmiṣanna fun ọrọ lọba-lọba ati Oniru funra ẹ, Ọba Ọmọgbọlahan Lawal.
Ninu lẹta to kọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, lo ti sọ pe oun gan-an ni gbogbo awọn eeyan ilu Iru fọwọ si gẹgẹ bii ẹni ti yoo di Oniru tuntun.
O ni sadeede ni Bọla Tinubu pe oun, to si sọ pe oun ko ni i le jọba ilu naa, nitori pe awọn ti oun n ba dowo pọ ko fọwọ si i koun jẹ ọba ilu Iru, ko yaa tete mu ọkan kuro nibẹ.
Ajasa sọ pe nibi ti wahala ti de ba oun niyẹn, ti Bọla Tinubu ati Gomina Eko, Babajide Sanwo-Olu, si da oun lagbo sina, lori bi wọn ṣe lọọ gbe ipo ọba fun Ọba Ọmọgbalọhan Lawal.
Ninu iwe apilẹkọ ti Amofin ẹ, Ishọla Agboọla, fọwọ si, lo ti sọ pe oun nikan ṣoṣo ni ọmọọba ti ẹbi Abisogun fa kalẹ fun ipo ọba ilu Iru, ṣugbọn niṣe ni Tinubu lọọ mu Lawal ti ko kopa ninu eto lati yan ọba tuntun fun ilu naa, to si sọ ọ di Oniru tuntun.