Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọdun kọkanlelogoji (41) ree ti agba ọjẹ olorin Apala nni, Oloogbe Waheed Ayinla Ọmọwura, ti jade laye. Eyi lo fa a ti ọkan pataki ninu awọn ọmọ ọkunrin naa, Queen Halimat Aṣabi Ayinla Ọmọwura, fi fẹẹ ṣe iranti naa l’Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ yii, l’Abẹokuta.
Gẹgẹ bi Halimat to ṣagbetẹru eto naa ṣe ṣalaye, Excellent Event Centre, loju ọna Kọbapẹ, ladojukọ Oluṣẹgun Ọbasanjọ Hiltop, GRA, Oke-Mosan, l’Abẹokuta, ni ayẹyẹ naa yoo ti waye.
Yatọ si ayẹyẹ iranti ti wọn tun pe ni ‘Ọmọwura Day’ yii, ọjọ yii kan naa ni Halimat toun naa n kọrin Apala bii baba rẹ, yoo ṣe ifilọlẹ awo orin tuntun to pe ni Apala Exraordinary, bẹẹ naa ni arẹwa obinrin yii yoo tun ṣe ifilọlẹ ajọ kan to pe ni Halimat Omowura Foundation.
Ninu atẹjade ti Aṣabi fi ṣọwọ s’ALAROYE lo ti jẹ ko di mimọ pe ilu Abẹokuta yoo gbalejo awọn gbajumọ olorin kaakiri ilẹ Yoruba lọjọ naa, bẹrẹ lati ori Ọba orin Juju, Oloye Sunday Adegẹye (KSA), Alaaji Kollington Ayinla, Alaaji Wasiu Ayinde, Adewale Ayuba, Salawa Abẹni, Ṣẹfiu Alao, Taye Currency, Saheed Oṣupa, Pasuma, Musiliu Haruna Iṣọla ati bẹẹ bẹẹ lọ. Bakan naa lawọn ọba alaye kaakiri ilẹ Yoruba ko ni i gbẹyin. Manigbagbe lọjọ naa yoo jẹ ninu itan gẹgẹ bi Halimat ṣe sọ.
Alagba Goke Babalọla ati Musiliu Sanni (Bẹbẹ) ni yoo dari eto lọjọ naa.