Stephen Ajagbe, Ilorin
Ijọba ipinlẹ Kwara ti paṣẹ pe kawọn ileewe mẹwaa kan di titi pa nitori wahala to n ṣẹlẹ lori lilo ibori ta a mọ si hijaabu fawọn ọmọleewe to jẹ Musulumi, paapaa awọn ileewe tajọ ẹlẹsin Kristẹni da silẹ, ṣugbọn ti wọn wa labẹ isakoso ijọba ipinlẹ Kwara.
Atẹjade kan latọwọ Akọwe agba ẹka to n mojuto eto ẹkọ ni Kwara, Arabinrin Mary Kẹmi Adeọṣun, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni awọn ileewe ọhun yoo ṣi wa ni titi na tijọba fi maa yanju wahala ti lilo ibori naa da silẹ.
Awọn ileewe ọhun ni; C&S College, Sabo Oke, ST. Anthony College, Ọffa Road, ECWA School, Ọja Iya, Surulere Baptist Secondary School, Bishop Smith Secondary School, Agba Dam, CAC Secondary School, Asa Dam, St. Barnabas Secondary School Sabo Oke, St. John School Maraba, St. Williams Secondary School, Taiwo Isalẹ, ati St. James Secondary School, Maraba.
ALAROYE gbọ pe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ileewe girama kan nigboro Ilọrin, Baptist LGEA School, le awọn akẹkọọ kan sita nitori pe wọn wọ hijaabu.
Lọna ati pana wahala naa, ijọba Kwara pe awọn adari ẹsin, Musulumi ati Kristẹni, sipade, lati jọ jiroro lori ẹ. Nibi ipade naa nijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ.
Awọn olori ẹsin naa gba ijọba nimọran lori bi wọn ṣe le yanju ọrọ naa lọna ti alaafia yoo fi wa.
Igbakeji gomina Kwara, Kayọde Alabi, lo dari ipade naa. O rọ awọn adari ẹsin mejeeji lati maa gbe pọ ninu ifẹ ki wọn si gba alaafia laaye.
O ni ki wọn fọwọsowọpọ lati tọ awọn ọmọ lọna ti wọn ko fi ni i maa ri ẹgbẹ wọn bii ọta.
Awọn to jẹ ọmọ igbimọ naa ni; Igbakeji gomina (Alaga), aṣoju mẹta-mẹta lati ẹsin kọọkan, adari ilu meji, Sẹnatọ Suleiman Ajadi, Ọmọọba Sunday Fagbemi; Akọwe agba ẹka eto idajọ ati lẹka eto ẹkọ, awọn Oluranlọwọ pataki fun gomina lori ẹsin (Kristẹni ati Musulumi), ati akọwe iroyin gomina Kwara.