Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti sọ pe oṣu mẹsan-an pere nijọba oun yoo fi ṣiṣẹ afara nla ti wọn fẹẹ ṣe si orita Ọlaiya, niluu Oṣogbo.
L’Ojọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni gomina sọrọ idaniloju naa lasiko to n ṣefilọlẹ iṣẹ afara naa. O ni afojusun ijọba lori rẹ ni lati din bi ijamba ọkọ ati ti ọkada ṣe maa n fi gbogbo igba ṣẹlẹ lorita nla naa ku.
Iṣẹ afara nla naa, eleyii tijọba gbe fun ileeṣẹ Messrs Peculiar Ultimate Concerns Limited, ni gomina sọ pe ijọba yoo na owo to le diẹ ni biliọnu mẹta naira (#3,108,379,829.76) le lori.
O ni ileeṣẹ to fẹẹ ṣe afara naa yoo kọkọ bẹrẹ iṣẹ lori rẹ, ko too di pe ijọba yoo bẹrẹ si i da owo naa pada diẹdiẹ kijọba le rowo gbọ bukata mi-in laarin ilu, eleyii ti wọn n pe ni Alternative Project Funding Approach).
Oyetọla fi kun ọrọ rẹ pe iṣẹ afara naa ko ni i da awọn iṣẹ idagbasoke yooku bii ipese eto-ẹkọ, eto ilera, idagbsoke eto ọrọ-aje, sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba, sisan owo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ati bẹẹ bẹẹ lọ duro rara.
O waa rọ awọn araalu lati fara da asiko yii pẹlu ijọba, niwọn igba to jẹ pe orita Ọlaiya naa bọ si aarin-gbungbun ilu Oṣogbo, o ni ki wọn maa fi suuru gba awọn ọna kọọkan tijọba ti ṣeto silẹ.
Ninu ọrọ ikini kaabọ rẹ, kọmiṣanna fun iṣẹ-ode ati igboke-gbodo ọkọ nipinlẹ Ọṣun, Ẹnjinnia Rẹmi Ọmọwaye gboṣuba fun afojusun rere ti gomina ni fun ipinlẹ Ọṣun lai fi ti bi eto ọrọ-aje ṣe da lagbaaye ṣe rara. O ni yatọ si pe afara naa yoo din ijamba ọkọ ku, yoo tun pinwọ sunkẹrẹ-fakẹrẹ lagbegbe naa.
Bakan naa ni alaga ileeṣẹ ti yoo ṣe afara naa, Abel Adeleke, fi da ijọba atawọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe iṣẹ naa ko ni i falẹ rara, yoo si jẹ alo-pẹ-pẹ-pẹ.