Faith Adebọla
Owe Yoruba to ni, ‘A ki i sọ fọmọde pe ko ma ṣe dẹtẹ, to ba ti le da inu igbo gbe’ lo wọ ọrọ ọdaran onijibiti ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni ‘Yahoo’, Micheal Ukoh Odeh. Adajọ ni eyi to gbatẹgun alaafia labẹ orule rẹ ti to gẹẹ pẹlu okoowo jibiti to n lu kiri, wọn ti ran an lẹwọn ọdun kan gbako, pẹlu iṣẹ aṣekara l’Abuja.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Onidaajọ O. A. Egwuatu, tile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa lagbegbe Maitama, niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, gbe idajọ naa kalẹ, ninu ẹjọ kan ti ajọ to n ri si iwa jibiti lilu, ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati awọn iwa ibajẹ mi-in, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC, pe tako ọdaran naa.
Ninu atẹjade kan ti ajọ EFCC ọhun fi lede, wọn ni latigba tawọn ti n gbọ finrin-finrin pe Micheal atawọn ẹlẹgbẹ rẹ kan n daṣọ bori huwa jibiti lori intanẹẹti niluu Makurdi, nipinlẹ Benue, ni wahala ti de ba ọdaran ọhun, lo ba bẹrẹ si i sa kaakiri, bi wọn ba gburoo rẹ si Ariwa loni-in, kilẹ too mọ, yoo ti tun dero Guusu, amọ sibẹ, ẹgbẹrun Saamu rẹ ko ribi sa mọ Ọlọrun lọwọ, wọn papa mu un nigbẹyin.
Lakolo EFCC, ni wọn ti ṣewadii rẹ, ti wọn si ba miliọnu mẹfa Naira ninu asunwọn banki rẹ, ni wọn ba ni ko ṣalaye bowo naa ṣe jẹ, iṣe wo lo ṣe, okoowo wo lo si da silẹ ti owo rẹpẹtẹ bẹẹ ṣe ṣodo sinu akaunti rẹ ọhun, amọ niṣe lọrọ pesi jẹ fun un. Nigbẹyin lo jẹwọ pe iṣẹ Yahoo-Yahoo tabi Yahoo plus loun n ṣe, ibi tawọn si ti n lu jibiti kiri loun ti rowo naa tu jọ.
EFCC ni iwa ti ọdaran naa hu ta ko isọri ogun, apa kin-in-ni ati ikeji iwe ofin to ta ko fifi owo ranṣẹ soke okun, eyi ti ijiya to gbopọn wa fun.
Nile-ẹjọ, ọdaran naa gba p’oun ti lufin, oun si jẹbi awọn ẹsun naa, n lagbẹjọro EFCC, Lọọya M. Yusuf, ba ni kile-ẹjọ ma tun fakooko ṣofo, ki wọn tete la a mọ gbaga. Eyi lo mu ki adajọ la a mẹwọn ọdun kan pẹlu iṣẹ aṣekara. Amọ Onidaajọ Egwuatu faaye sisan owo itanran silẹ fun ọdaran yii, wọn ni ko san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (N300,000) fun ijọba lara owo to lu jibiti rẹ, o si tun gbọdọ san iye owo yii kan naa gẹgẹ bii owo itanran.
Adajọ tun paṣẹ ki wọn gbẹsẹ le foonu Infinix 7 ati awọn dukia mi-in, wọn lowo eru lo fi ko wọn jọ.