Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọmọ iya meji ki i rewele lowe ti Yoruba maa n pa, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ fun awọn ọmọ iya meji kan ti wọn jẹ ibeji, Olusọji Taiwo ati Kehinde Olusọji, ti wọn ti ri ju ewele lọ bayii pẹlu bi wọn ṣe lọọ digunjale, ti ọwọ si tẹ wọn nibi ti wọn ti lọọ fọ ṣọọbu laduugbo Mathew, ni Odo-Ado, l’Ado-Ekiti.
Nigba ti Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Akinwale Adeniran, n ṣafihan wọn fawọn oniroyin, o ṣalaye pe yatọ sawọn ibejì ọran ti wọn yan iṣẹ fọle-fọle laayo yii, ọwọ awọn tun tẹ awọn meji miiran ti wọn maa n gba ọja ole silẹ lọwọ awọn ibeji meji yii, iyẹn Afọlayan Funkẹ ati Nnaji Benignus, ti wọn si ti n sọ tẹnu wọn lakata awọn agbofinro bayii.
Adeniran ni ọwọ ẹka kogberegbe ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti tẹ awọn ibeji yii lẹyin ti wọn fọ ṣọọbu kan tan ni adugbo Matthew, ni Odo-Ado, ti wọn si ko gbogbo ẹrun to wa ninu ṣọọbu naa lọ.
Lakooko ti awọn ọlọpaa fọrọ wa wọn lẹnu wo, wọn jẹwọ pe loootọ lawọn fọ ṣọọbu mẹta ni adugbo naa, ti wọn si tun ni awọn lawọn fọ awọn ṣọọbu miran ni ọja Fayẹmi, laduugbo Agiriki Ọlọpẹ.
Lara awọn nnkan ti wọn jẹwọ pe awọn ji ni apo ẹwa meji, apo irẹsi meji, ati awọn ẹrun miiran ti owo fẹrẹ to miliọnu kan Naira (N936,750,00) .
Kọmiṣanna ṣalaye siwaju si i pe ninu itọpinpin ti awọn ọlọpaa ẹka ọtẹlẹmuyẹ ṣe ni wọn ti ṣawaari awọn meji ti wọn n gba ọja ole lọwọ awọn ibeji naa.
Ọga ọlọpaa yii fi kun un pe gbogbo awọn ọdaran naa ni wọn wa ni atimọle lọwọlọwọ, ti wọn si n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadi ati itọpinpin wọn lori iṣẹlẹ naa.
O fi kun un pe awọn ibeji naa at’awọn onibaara wọn yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ naa.