Ibi ayẹyẹ igbeyawo lawọn kan ti n bọ ti wọn fi ji marun-un ninu wọn gbe ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin 

Inu idaamu ati iporuuru ọkan ni awọn eeyan Agboolé Igbẹdẹ, niluu Odó-Ọwá, nijọba Ibilẹ Oke-Ẹrọ, nipinlẹ Kwara, wa bayìí. Eyi ko sẹyin bi awọn agbebon kan ṣe ji marun-un nínú mọlẹbi wọn gbe lọ, tí wọ́n sì ń béèrè fún ọgọ́rùn-ún kan milionu Náírà gẹgẹ bii owo itusilẹ.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejìlá, ọdun 2024 yii, ni awọn ajinigbe jí wọn gbe lasiko ti wọn dari bọ láti ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó ti wọn lọ ní nǹkan bíi aago mẹrin irọlẹ ọjọ ọhun.

Ọkan lara awọn mọlẹbi sọ pe awọn arinrin-ajo marun-un ni wọn n dari bọ lati Ọ̀gbẹ̀, nipinlẹ Kogi, nibi ti wọn ti lọọ ṣe ayẹyẹ igbeyawo, ti wọn si n pada si Odo-Ọwa, nipinlẹ Kwara. Ṣugbọn lopopona Obbo Ayegunlẹ, lawọn ajinigbe naa to dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro ti da wọn lọna, ti wọn si n yinbọn soke ko too di pe wọn ji marun-un gbe lọ ninu wọn.

Wọn ti pe awọn mọlẹbi báyìí, ti wọn si n beere fún ọgọ́rùn-ún miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ, èyí to mu kí gbogbo ilu maa dawo jọ.

Orúkọ àwọn ti wọn ji gbe ọhun ni Oloye Oyewọle Abọlarin, to jẹ Oluọdẹ ati ìyàwó rẹ, Funmilayọ Abọlarin, Tunde Ọladipọ ati iyawo rẹ, Yinka Ọladipọ, to fi mọ Aina Bọṣẹ.

Wọn ti waa rawọ ẹbẹ si Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ati awọn ẹṣọ alaabo lati rán wọn lọwọ ki wọn le kuro lahaamọ awọn ajinigbe ọhun layọ ati àlàáfíà.

Nigba ti ALAROYE pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Adetoun, boya wọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa, o ni oun ko ti i gbọ, sugbọn oun yoo ṣe iwadii lori rẹ.

 

Leave a Reply