Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni awọn agbebọn ti wọn o ti i mọ ji Mọgaji Erubu, Dokita Zubair Ọba Fọlọrunshọ, gbe lọ niluu Agọ Ọja, nijọba ibilẹ Afọn, nipinlẹ Kwara.
Ohun ti ALAROYE gbọ lẹnu mọlẹbi ọkunrin naa ni pe aṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ti Fọlọrunshọ n bọ lati ibi iṣẹ oojọ rẹ ni awọn agbebọn to dihamọra pẹlu ohun ija oloro da a lọna niwaju ita ile ẹ, ti wọn si n yinbọn leralera lati fi dẹruba awọn olugbe agbegbe naa, ti wọn si pada ji i gbe lọ.
Fọlọrunshọ ni akọwe agba fun ipinlẹ Kwara tẹlẹ, to si tun jẹ Dokita nileewosan aladaani kan to n jẹ Fadima, to wa l’Opopona Balogun Fulani, niluu Ilorin.
Ọmọ bibi ilu Ilọrin, ni Mọgaji Erubu, titi di igba ta a n ko iroyin yii jọ, awọn ajinigbe naa ko ti i kan si mọlẹbi ọkunrin naa.