Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ṣinkun bayii lọwọ tẹ awọn baale ilẹ mẹta yii torukọ wọn n jẹ Jẹlili Waheed, Ọtun Taye ati Olu Adeniran, nibi ti wọn ti n fọ ile ikẹru-si ileeṣẹ nla kan ni Àgbárá, nijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, nipinlẹ Ogun.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ yii, lọwọ ọlọpaa teṣan Agbara tẹ wọn, lẹyin ti olobo ta wọn pe awọn eeyan kan ti gbe mọto akẹru wa, wọn si ti n ko awọn ọja ileeṣẹ naa sọkọ ọhun, wọn fẹẹ ko o sa lọ.
Nnkan bii aago mẹrin irọlẹ lawọn ọlọpaa naa dọdẹ awọn eeyan yii debẹ, wọn si ba wọn nibi ti wọn ti n ba awọn nnkan kan jẹ ki wọn le ri ohun ti wọn fẹẹ gbe jade.
Awọn jẹnẹretọ nla meji meji ni wọn ti gbe sinu ọkọ Iveco to ni nọmba AKD 747XZ ti wọn gbe wa, wọn si tun gbe kinni kan ti wọn n pe ni’Fork lift’ naa si i.
Awọn nnkan yii pẹlu mọto ti wọn fi kẹru naa lawọn ọlọpaa gba lọwọ wọn, wọn si ti taari awọn mẹtẹẹta si atimọle, iwadii ti bẹrẹ lori wọn pẹlu, lati mọ iru itu ole jija ti wọn ti pa ri kọwọ too tẹ wọn lọtẹ yii.