Faith Adebọla, Eko
Ibi ti afurasi ọdaran eni ọdun mẹrinlelogun kan, Korede Anifowoṣe, ti fẹẹ ja Ṣọla Musa lole n’Ipaja, nipinlẹ Eko, lọwọ awọn agbofinro ti tẹ ẹ, laṣiiri ẹ ba tu pe ki i ṣe kọsitọma gidi rara, adigunjale pọnbele ni.
Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣe sọ f’ALAROYE ninu atẹjade to fi ṣọwọ si wa, o ni awọn to n ṣiṣẹ ni teṣan Ipaja ni wọn mu Korede lopin ọsẹ to kọja yii, ati pe meji ni wọn jọ n rin, ẹni keji ẹ ti wọn jọ n jale kiri Eko ti sa lọ, awọn ṣi n wa a bayii.
Wọn niṣe lọkunrin naa kọkọ ṣe bii ẹni to fẹẹ fi kaadi ATM gba owo lori ẹrọ iṣiro ti Ṣọla n lo, aṣe o ti foju ṣọ ibi tọmọbinrin naa n gbe apo owo ẹ si, ojiji lo ki baagi owo naa mọlẹ, to si fẹẹ ju u si ẹni keji ẹ to ti sun mọ tosi nigba yẹn.
Nigba ti Ṣọla fẹẹ pariwo, niṣe ni Korede fabọn yọ si i, to si paṣẹ fun un pe ko dakẹ, ṣugbọn ọmọbinrin naa figbe ta pe kawọn araadugbo gba oun, lawọn eeyan ba sare debẹ.
Boya awọn eeyan to tete debẹ yii lori fi ko Ṣọla yọ, tori wọn gba Korede mu, wọn din dundu iya fun un, kawọn ọlọpaa to n ṣe patiroolu too de sasiko naa, wọn gba ibọn ọwọ ẹ ati katiriiji ọta ibọn to wa lapo ẹ, wọn si wọ afurasi ọdaran naa ju si mọto wọn.
Adejọbi ni Korede ti wa ni Panti, Yaba, lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fun