Ibi ti mo gbe iṣẹ ọlọpaa de daa ju bi mo ṣe ba a lọ-Usman Baba

Adewale Adeoye

‘Eyi ti mo ṣe nidii iṣẹ ọlọpaa ilẹ wa to gẹẹ, inu mi si dun gidi pe mo gbe awọn akọ iṣẹ kọọkan ṣe nileeṣẹ ọlọpaa orileede yii latigba ti mo ti depo ọga agba lati ọdun 2021. Mo le fọwọ rẹ sọya daadaa pe mo ti gbe e debi ti ẹru ko ti ni i ba awọn ẹni to n bọ lẹyin mi lati maa tẹsiwaju bayii. Ebute ayọ ni mo fori iṣakooso ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa sọ bayii, inu mi si dun gan-an ni pẹlu awọn aṣeyọri ti mo ni nidii iṣẹ naa’.

Eyi gan-an lọrọ to n jade lẹnu ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii tẹlẹ, Ọgbẹni Usman Baba, lakooko to n fipo rẹ silẹ gẹgẹ bii olori ileeṣẹ ọlọpaa orileede wa l’Ọjọbọ, Tọsideee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Ninu ọrọ rẹ lakooko to n ko awọn ẹru ijọba gbogbo to wa lọwọ rẹ silẹ fun Ọgbẹni Kayọde Ẹgbẹtokun, ẹni ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo adele ọga ọlọpaa l’Abuja, ni Usman ti sọ pe pẹlu inu didun loun fi le sọ nita gbangba pe ibi to daa loun gbe iṣẹ ọlọpaa orileede yii de lakooko toun fi wa nipo naa, ati pe gbogbo erongba oun pata lati yi orukọ aburu ti wọn ti mọ mọ ileeṣẹ ọhun atawọn to n ṣiṣẹ naa loun ri i daju pe oun mu ṣẹ lakooko toun fi wa nipo olori ileeṣẹ naa.

Lara awon ohun ti Usman loun ri i daju pe oun gbe ṣe ni pe oun ri i pe igbe aye idẹrun wa fawọn ọlọppaa gbogbo ti wọn wa lẹnu iṣẹ lọwọ, iya ko si jẹ awọn ẹbi wọn.

Siwaju si i Usman ni, ‘’Nnkan pọ gidi ti mo ti gbe ṣe lakooko iṣakooso ijọba mi. Lara rẹ ni ipese ojulowo irinṣẹ tawọn ọlọpaa nilo lati jẹ ki iṣẹ wọn rọrun. Bakan naa ni mo ri i daju pe awọn ọlọpaa ẹka oju omi ati ti oju ofurufu paapaaa ri awọn ohun ti wọn nilo gba lasiko. Bẹẹ ni mo pese awọn ojulowo irinṣẹ kan to jẹ pe awọn ọlọpaa paapaa ko ri lo lati aimọye ọdun sẹyin, eyi to mu ki iṣẹ wọn rọrun daadaa’’.

Ni ipari ọrọ rẹ, Usman waa dupẹ lọwọ gbogbo awọn alabaaṣiṣẹ-pọ rẹ bi gbogbo wọn ṣe ṣiṣẹ naa daadaa, ti ko fi kabaamọ lakooko to fi wa nipo olori ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa.

Ninu ọrọ tiẹ, Adele ọga ọlọpaa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Ọgbẹni Kayọde Ẹgbẹtokun, fi da gbogbo ọlọpaa orileede yii loju pe oun yoo ṣohun gbogbo lọna tiṣẹ naa yoo gba rọ wọn lọrun ju ti atẹyinwa lọ.

O ni gbogbo ohun to wa nikaawọ oun pata loun maa ṣe lati ri i pe ibi giga tawọn araalu mọ ileeṣe ọlọpaa orileede wa si ni yoo wa nigba gbogbo. Ti igbega si ti daadaa yoo si de ba awọn to n ṣiṣẹ naa laipẹ ọjọ.

Leave a Reply