Adewale Adeoye
Titi di asiko taa n koroyin yii jọ, ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Onikan, nipinlẹ Eko, ni afurasi ọdaran kan, Yakubu Yusuf, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ti wọn fẹsun iwa ọdaran kan wa. Afaimọ ko ma jẹ ibẹ lo maa gba lọ si kootu.
ALAROYE gbọ pe ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni ọmọkunrin yii atawọn ọrẹ rẹ kan tawọn ọlọpaa agbegbe naa n wa bayii lọ sori biriiji ẹlẹsẹ kan to wa lẹgbẹẹ ileewe ẹkọṣẹ iṣegun awọn nọọsi lagbegbe Third Mainland Bridge, l’Ekoo, wọn lọọ ji awọn irin tijọba ṣe sẹgbẹẹ biriiji naa yọ, lasiko ti wọn n yọ awọn irin ọhun lọwọ lawọn agbofinro tawọn araalu pe fọwọ ofin mu Yakubu, tawọn yooku rẹ si sa lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe DPO teṣan ọlọpaa agbegbe Onikan, nipinlẹ Eko, lo ṣaaju ikọ akanṣe kan lọ sibi tawọn agbofinro ti fọwọ ofin mu Yakubu.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe, ‘’Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Yakubu atawọn ọrẹ rẹ kan lọọ ji irin ori biriiji ẹlẹsẹ kan, awọn araalu lo pe ọlọpaa lori foonu, ti wọn si waa fọwọ ofin mu wọn. Yakubu nikan lọwọ tẹ, awọn yooku rẹ sa lọ’’.
Alukoro ni iwadii n lọ lọwọ lati fọwọ ofin mu awọn to sa lọ yii, lẹyin naa ni wọn maa foju gbogbo wọn bale-ẹjọ .