Florence Babaṣọla, Osogbo
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Ọṣun, ti bu ẹnu atẹ lu aṣẹ ti Ataọja ilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Ọlanipẹkun, pa fun awọn ajeji to n gbenu ilu naa laipẹ yii pe awọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP nikan ni wọn gbọdọ dibo fun ninu idibo apapọ to n bọ.
Ninu atẹjade kan ti Adele alaga ẹgbẹ naa, Sooko Tajudeen Lawal, fi sita lo ti sọ pe laipẹ yii ni Ataọja pe awọn adari ẹya Hausa, Igbo, Fulani ati Ebira sipade kan laafin rẹ.
Ipade naa, eleyii ti adari ẹya Igbo ko lọ, ni Lawal ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi to ta ko ẹtọ awọn eeyan ọhun lati dibo fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹ oṣelu to ba wu wọn.
O ni igbesẹ Ataọja yii ko jọ oun loju nitori ko figba kankan fi ainifẹẹ ẹgbẹ oṣelu APC pamọ ri ninu iwa ati iṣe rẹ, idi si niyẹn ti ko fi ki Oyetọla ku oriire lẹyin ti kootu ni ki wọn gba satifikeeti lọwọ Gomina Ademọla Adeleke.
Lawal waa parọwa si gbogbo awọn ẹya ti wọn ki i ṣe Yoruba niluu Oṣogbo lati taari aṣẹkaṣẹ ti ẹnikẹni ba pa lodi si ẹtọ wọn labẹ ofin danu.
Bakan naa lo rọ Ataọja lati ri ara rẹ bii baba fun gbogbo awọn oloṣelu, lai fi ti ẹgbẹ ti wọn n ṣe ṣe lati le dena wahala ti ko nitumọ.