Ibo 2023: Tinubu ati Atiku gbọdọ ṣayẹwo ilera wọn ati mimu oogun oloro-Melaye

Jọkẹ Amọri  

Agbẹnusọ fun ikọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Dino Melaye, ti sọ pe afi ki ileeṣẹ to n gbogun ti lilo ati gbigbe egboogi oloro nilẹ wa, NDLEA, ṣayẹwo fun awọn meji to n lewaju ju ninu awọn to fẹẹ dije dupo aarẹ Naijiria, Alaaji Atiku Abukar to fẹẹ dije ninu ẹgbẹ PDP, ati Aṣiwaju Tinubu to fẹẹ dije ninu ẹgbẹ APC, ki wọn si gbe esi ayẹwo naa si gbangba ki aye ri i.

O ni eleyii yoo jẹ ki gbogbo aye mọ bi wọn ṣe kun oju oṣuwọn si lati le ṣiṣẹ takuntakun lori ipo ti wọn fẹẹ bọ si yii.

 Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Kogi yii sọrọ naa lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla yii. Melaye ni, ‘‘Mo n pe awọn oludije mejeeji to n lewaju ju lọ ninu eto idibo ọdun to n bọ pe ki wọn fa ara wọn kalẹ fun ilera ara wọn ati ayẹwo boya wọn n mu oogun oloro abi wọn o ki i mu un. Mo n fi asiko yii pe alaga ajọ to n gbogun ti tita ati lilo oogun oloro nilẹ wa, Buba Marwa, lati ṣayẹwo fun awọn oludije mejeeji yii nitori ẹnikẹni ti yoo ba jẹ aarẹ ilẹ wa gbọdọ wẹ ko yan kain-kan-in lori ọrọ lilo oogun oloro, ka si mọ ipo ti ilera rẹ wa. Eleyii ṣe pataki pẹlu bi ilẹ wa ṣe n koju wahala oogun oloro lilo lasiko yii.

‘‘Gbogbo ẹnu ni mo le fi sọ ọ pe ailera Tinubu ko pe to. Mo pe e nija lati ṣe ayẹwo ilera rẹ, ko si gbe e jade. Atiku naa yoo se tirẹ. A fẹẹ mọ boya bo ṣe n sọrọ agbado ati ẹgẹ pẹlu awọn ọdọ ile wa bii aadọta miliọnu to ni ki wọn gba si iṣẹ ṣọja, jẹ ọrọ to sọ lasan tabi afihan pe ilera rẹ ko pe daadaa.

‘‘Oluwosan ni ile ijọba ni Aso Rock n wa, ki i ṣe alaaarẹ. Naijiria ko fẹ aarẹ ti yoo tun maa paara London losọọsẹ fun ilera rẹ, eyi ti ko ni i jẹ ko raaye mojuto eto ọrọ-aje ati iṣẹ ilu gbogbo’’.

Bẹẹ lo fi kun un pe oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi paapaa ko ni ohun to pe fun lati jẹ aarẹ ilẹ wa. Bo tilẹ jẹ pe o gboṣuba rabandẹ fun ọkunrin naa fun iṣẹ akin to n ṣe, o ni pẹlu ẹ naa, ipo aarẹ ko ti i kan an. Melaye ni Obi ko ni agbara lati jẹ ki orileede yii wa ni iṣọkan, O ni o jẹ ohun ti ko dara, bi eeyan ba gbe iṣẹ kafinta fun telọ. O yẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ pe ibo yoowu ti wọn ba di fun Obi, APC ni wọn di i fun nitori Obi ko le debẹ.

O fi kun un pe ẹnikẹni to ba n polongo ibo fun Obi, Tinubu lo n ṣiṣẹ fun lati di aarẹ ilẹ wa. Bakan naa lo sọko ọrọ si Fẹmi Fani-Kayọde, pẹlu bo ṣe ni eeyan Ọlọrun ti a ran lati waa gba ilẹ wa silẹ ni Tinubu ati igbakeji rẹ, Shettima. O ni ọkunrin na ko mọ ohun to n sọ, ati pem idakeji ohun to ni lọkan lo n sọ jade.

 

Leave a Reply