Monisọla Saka
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni ọga agba ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, Mahmood Yakubu, gba iwe ẹsun tawọn ẹgbẹ oṣelu PDP, kọ ta ko o lori eto idibo aarẹ atawọn aṣofin to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii. Wọn ni bo tilẹ jẹ pe ajọ naa ṣe adehun pe gbogbo kudiẹ-kudiẹ to waye lasiko ibo naa lawọn yoo wa ojutuu si, wọn o ti i gbe igbesẹ kankan sibẹ naa.
Yakubu ti Kọmiṣanna to n mojuto ilanilọyẹ nipa ibo didi nilẹ yii, Festus Okoye, ṣoju fun, sọ pe ajọ naa ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu ẹgbẹ oṣelu kankan nilẹ yii.
Niṣe lawọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP to lọ si ọfiisi ajọ eleto idibo naa sọ ija kalẹ nigba ti wọn ta ku pe awọn ko ni i gba iwe ẹsun ọhun. Eyi lo mu ki oludije funpo aarẹ lẹgbẹ wọn, Alaaji Atiku Abubakar, atawọn to ko sodi lọ si ọfiisi INEC, ti wọn ṣewọde ifẹhonu han ọhun niluu Abuja, taku pe awọn o ni i kuro nibẹ, afi ti wọn ba gbawe ẹsun ọhun lọwọ awọn.
Nigba to n sọrọ lẹyin to tẹwọ gba iwe ẹsun naa tan lọwọ wọn, Okoye ni, “Mo gba iwe ifẹhonu-han yii lorukọ alaga ajọ INEC, mo si ṣeleri fun yin pe ma a jẹ ki lẹta yii tẹ wọn lọwọ, ti awọn nnkan kan ba wa to n fẹ atunṣe, a o wa nnkan ṣe si i”.
Bakan naa ni Okoye fi wọn lọkan balẹ pe eletiigbaroye nileeṣẹ naa, ati pe ileeṣẹ ijọba ni, ti awọn ọmọ Naijiria naa si ni i ṣe. Bẹẹ lo fi kun un pe ilẹ Naijiria lawọn n ṣiṣẹ fun, ko si ohunkohun laarin awọn ati ẹgbẹ oṣelu kankan.
Ninu iwe ẹsun ti ajọ ẹgbẹ oṣelu PDP kọ ta ko ajọ INEC, eyi ti alaga ẹgbẹ naa, Iyorchia Ayu ati Samuel N. Anyanwu, ti i ṣe akọwe apapọ ẹgbẹ naa buwọ lu, ni wọn ti ni, “Lẹyin ọpọlọpọ ipade lati le wo abajade esi idibo aarẹ ati tawọn aṣofin to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, a ri i pe o ṣe pataki ka ba yin sọrọ, to fi mọ awọn eekan mi-in ti wọn n lọwọ ninu idagbasoke ijọba awa-ara-wa lorilẹ-ede Naijiria, lati le mọ ipo ti ẹgbẹ wa ṣe pẹlu bi wọn ṣe ṣe eto idibo ọhun ati esi ti wọn kede faye gbọ”.
” O yẹ kẹ ẹ ranti ariwo ti pupọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii tọrọ naa ka lara n pa lori bi wọn ṣe n naka aleebu si yin pẹlu eto idibo tẹ ẹ daru nitori ẹgbẹ APC. Nigbakuugba tọrọ naa ba si rapala wọ ori ẹrọ ayelujara lẹ ti maa sare yi i pe irọ ati ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ ni wọn fi kan yin. Lonii, awọn ọmọ Naijiria si ti waa ri i pe ootọ ni gbogbo awọn ẹsun yẹn”.
Awọn ẹgbẹ oṣelu yii fi ẹdun ọkan wọn han pe, eto idibo tawọn ọmọ Naijiria ti fọkan balẹ le lori pe awọn yoo fi ri ayipada ninu eto idibo lorilẹ-ede yii lo pada waa di yẹbẹyẹbẹ yii.
Awọn PDP ni adehun ti alaga ajọ INEC ṣe fawọn ọmọ Naijiria ni pe oun yoo ṣe eto idibo ti yoo lọ nirọwọ-rọsẹ, to yatọ si ti atẹyinwa, lai ni i figba kan bọkan ninu labẹ iṣakoso oun.
“Bakan naa lo tun ṣeleri pe ẹ maa lo ẹrọ igbalode BVAS, lati fi ṣe ayẹwo orukọ awọn oludibo, ati lati gbe esi idibo sori afẹfẹ, nibi tawọn araalu yoo ti maa wo gbogbo esi idibo bo ba ṣe n lọ. Ṣugbọn to jẹ pe ẹ ko mu ileri yii ṣẹ.
Ninu lẹta ti Iyorchia Ayu, ti i ṣe alaga ẹgbẹ naa mu wa yii ni wọn ti sọ fun ajọ INEC pe bi wọn ṣe ṣeto idibo ati abajade ẹ ko jẹ itẹwọgba fawọn ọmọ Naijiria, nitori o kere jọjọ si ohun ti wọn n reti.
Ninu nnkan marun-un ti wọn beere lọwọ ajọ naa ninu iwe ẹsun yii ni wọn ti sọ pe awọn ko gba esi idibo aarẹ ti ajọ naa kede wọle. Wọn ni ẹlẹẹkeji ni pe awọn n ke si ajọ INEC lati dawọ esi idibo ti wọn n gbe sori ẹrọ ayelujara wọn duro, nitori o ta ko ofin eto idibo ọdun 2022.
Bakan naa ni wọn lawọn tun n lo anfaani ọhun lati kilọ fun ajọ INEC, lati ma ṣe dan iru nnkan ti wọn dan wo lasiko ibo aarẹ inu oṣu Keji, ọdun yii, wo lọjọ ibo gomina atawọn aṣofin ipinlẹ ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii, wọn ni awọn a ba wọn na an tan bii owo ti wọn ba fẹẹ gbidanwo ati ṣe magomago kankan.
Ninu koko kẹrin ni wọn ti ke si awọn ọmọ Naijiria, lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn lati ja fun ijọba awa-ara-wa lori ọrọ ibo, ofin ilẹ yii ati ẹtọ wọn lati dibo yan ẹnikẹni to ba wu wọn.
Ibeere ẹlẹẹkarun-un ni ki ajọ naa ṣalaye idi ti wọn ṣe kede esi idibo pẹlu gbogbo kudiẹ-kudiẹ to foju han nibẹ, lẹyin tawọn eeyan ti pe wọn si akiyesi lati ṣe atunṣe lasiko ti wọn n ṣe e lọwọ ati ṣaaju igba naa.
Bakan naa ni Ayu tun ni, “Gbogbo igbagbọ ta a ni ninu rẹ lati ṣe eto idibo to gbounjẹ fẹgbẹ, to gbawo bọ, ni iwọ atawọn oṣiṣẹ ẹ ti fi abosi bajẹ, ko si sẹni to le fọkan tan ọ mọ. Inu tilẹ n bi awọn araalu pẹ̀u ikede to o fi abosi pilẹ rẹ ọhun, wọn o si fi eyi bo”.
O ni lai fọrọ sabẹ ahọn sọ, ninu itan ilẹ Naijiria, eto idibo aarẹ to kọja yii jẹ eyi tawọn eeyan ji giri si, ti wọn si fi gbogbo agbara wọn si lati ibẹrẹpẹpẹ lojuna ati le ṣe ojuṣe wọn, amọ nnkan ti Yakubu ṣe yii ti ko irẹwẹsi ọkan ba wọn.