Jọkẹ Amọri
Bi ibo abẹle APC ṣe n sun mọ etile, awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa ti tun yọ kuro ninu orukọ awọn ti yoo dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn. Gomina ipinlẹ Plateau Simeon Lalong lo sọ eleyii di mimọ laaarọ ọjọ Isẹgun, Tusiodee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa ti eto idibo naa yoo waye.
Ni bayii, dipo mẹtadinlogun ti wọn ni tẹlẹ, wọn ti ge e ku si marun-un. Eyi ko sẹyin ipade ti Buhari ṣe pẹlu awọn gomina, nibi to ti sọ fun wọn pe ki wọn din awọn oludije naa ku.
Awọn marun-un ọhun ni Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Aṣiwaju Bọla Tinubu, Gomina Kayọde Fayẹmi, Rotimi Amaechi ati Gomina Dave Umahi.
Lalong ni awọn ti ko orukọ naa lọ siwaju Aarẹ Buhari, o si ti fọwọ si i.