Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi, ti ki Eyitayọ Jẹgẹdẹ ku oriire fun bo ṣe jawe olubori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ PDP to waye lanaa niluu Akurẹ.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Allen Soworẹ, fi sita ni lẹyin idibo ọhun, eyi to pe akọle rẹ ni, ‘a ti ja ija rere’ lo ti dupẹ lọwọ awọn eeyan fun atilẹyin ti wọn ṣe fun un lasiko eto ibo naa.
Ajayi ni oun ti gba f’Ọlọrun, niwọn igba tawọn oludibo tí fi ibo wọn juwe ibi ti wọn n lọ.
O ni, oun ṣi duro lai yẹsẹ lori ipinnu oun lati ri i daju pe ìjọba awa-ara-wa fẹsẹ mulẹ nipinlẹ Ondo, yatọ si ijọba adanikanṣe to wa lori aleefa lọwọ.
Oludije mi-in, Ọlabọde Ayọrinde naa ti ki Amofin Jẹgẹdẹ ku oriire, o si tun gbadura pe k’Ọlorun ti i lẹyin ko le ṣe aṣeyọri ninu awọn igbesẹ to ku niwaju.