Ibo abẹle PDP l’Ọṣun: Ademọla Adeleke jawe olubori, oun ni yoo koju Oyetọla ti ẹgbẹ APC

Gbenga Amos

Ondije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun lorukọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) lọdun 2018, to tun figba kan jẹ aṣofin agba nilẹ wa, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ni yoo dupo gomina lorukọ ẹgbẹ PDP ninu eto idibo ti yoo waye loṣu Kẹfa, ọdun yii, nipinlẹ naa.

Adeleke lo jawe olubori ninu eto idibo abẹle ti ẹgbẹ oṣelu naa ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta yii, ni papa iṣere ilu Oṣogbo, Oṣogbo, latari bo ṣe jẹ oun lo ni ibo to pọ ju lọ, nibi ti wọn ti yan ọmooye ẹgbẹ naa.

Ibo ẹgbẹrun kan, ọgọrun-un mẹjọ ati mẹtadinlaaadọrun-un (1,887) ni Adeleke ni, nigba ti Ọgbẹni Sanya Omirin, to tun nibo to pọ ṣikeji, ni ibo mẹrin (4) pere. Ibo kan ṣoṣo pere ni Ọgbẹni Dele Adeleke to wa nipo kẹta ni, nigba ti awọn mẹta yooku, Fatai Akinbade, Dọtun Babayẹmi, Akin Ogunbiyi ko ni ibo kankan.

Igbakeji gomina ipinlẹ Bayelsa, Sẹnetọ Lawrence Ewurujakpo, to ṣe alaga igbimọ to dari eto idibo abẹle naa kede pe aropọ ibo ẹgbẹrun kan, ọgọrun-un mẹsan-an ati ẹyọ mẹrindinlogun lawọn aṣoju to pesẹ sibẹ di, ibo mẹrinlelogun (24) ni wọn ko wulo, o si kede Ademọla Adeleke bii olubori.

Pẹlu iṣẹlẹ yii, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ati Gomina Adegboyega Oyetọla ti ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo jọ figa gbaga, pẹlu awọn ondije yooku latinu awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in, lasiko ti eto idibo naa ba waye.

Leave a Reply