IBO APC: AKEREDOLU LO WỌLE

Ibo abẹle APC ti wọn di lanaa ni ipinlẹ Ondo, Gomina Rotimi Akeredolu lo ma wọle.  Iyẹn ni pe ẹmi Gomina naa ti de bayii pe oun loun yoo tun du ipo lẹẹkeji lorukọ ẹgbẹ oṣelu oun.

Awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu yii to pejọ si gbọngan nla Event Center ni Alagbaka, Akurẹ, le ni ẹgbẹtala (2,600), ti wọn fẹẹ mu ninu awọn mọkanla to ti jade tẹlẹ pe awọn ni ki ẹgbẹ fa kalẹ. Ṣugbọn nigba ti wọn dibo naa tan, o le ni egbejila (2,458) ibo ni Akeredolu nikan da mu, ẹni to si sun mọ ọn ju ni Oloye Oluṣọla Oke to mu ọtalerugba le meji (262) ibo. Oloye Kekemeke naa ni ibo mọkandinlogun, ṣugbọn oun ti sọ pe oun ko ṣe mọ tẹlẹ o.

Ni bii aago kan oru ku diẹ ni wọnkede esi idibo naa, nibi ti Gomina Yahya Bello olati ipinlẹ kogi ti je alaga wọn. Ko si giri mọ bayii, ki Akeredolu maa mura silẹ fun ibo gomina ninu oṣu kẹwaa lo ku o.

Leave a Reply