Ibo Ekiti: Ile-ẹjọ da Oyebamiji lare, wọn da ẹjọ Ṣẹgun Oni nu

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ati awuyewuye lẹyin idibo nipinlẹ Ekiti, ti da ẹjọ ti Oloye Ṣẹgun Oni pe lati ta ko jijawe olubori, Ọgbẹni Biọdun Oyabamji, gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.

Ṣẹgun Oni to jẹ oludije ẹgbẹ Ẹlẹsin, (SDP), lo pe ẹjọ ta ko jijawe olubori Oyebanji to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, ni kete ti ajọ eleto idibo kede pe ọkunrin naa lo wọle ninu eto idibo to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.  Igbimọ ẹlẹni mẹta naa sọ pe Ṣẹgun Oni ko ni ẹri to daju niwaju awọn lati le Biọdun Oyebanji kuro lori ipo naa.

Ninu iwe ti oludije ninu ẹgbẹ Ẹlẹṣin naa fi pe ẹjọ lo ti sọ pe ki wọn kede oun gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa, o ni oun gan-an loun ni ibo to pọ ju ninu eto idibo ọhun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Alaga igbimọ naa, Onidaajọ Wilfred Kpochi, sọ pe Oyebanji gan-an lo jawe olubori ninu eto idibo to waye ọhun gẹgẹ bii ajọ eleto idibo ṣe kede rẹ.

Bakan naa ni awọn ọmọ igbimọ to ku, Onidaajọ Sa’ad Zadawa ati J.A Atsen, sọ pe Oloye Ṣẹgun Oni ati ẹgbẹ rẹ, SDP, ti kuna lati fi idi rẹ mulẹ pe eto idibo ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, naa lo waye pẹlu ibo rira ati ẹsun mago-mago miiran gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ninu iwe ti wọn fi pe ẹjọ yii.

Ile-ẹjọ naa tun da a pe ẹgbẹ Ẹlẹsin kuna lati ko ẹri to daju siwaju ile-ẹjọ naa.

Lori ẹsun pe Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, ko yẹ ko wa ni ipo gomina ko tun jẹ alaga ẹgbẹ Onigbaalẹ ni akoko kan naa, ti ko si yẹ ko buwọ lu iwe fun Oyebanji ni akoko naa gẹgẹ bii oludije, Onidaajọ Kpochi ni ile-ẹjọ naa ko ni agbara lati gbọ ẹsun yii, pẹlu idi pataki pe eleyii ti yẹ ko waye ki eto idibo naa too waye.

Onidaajo Kpoch ṣalaye pe ẹgbẹ Ẹlẹṣin ko ni anfaani lati pe ẹjọ ta ko igbesẹ yii, nitori pe ẹgbẹ Onigbaalẹ nipinlẹ Ekiti ti dibo yan Oyebanji gẹgẹ bii ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ wọn lakooko idibo naa.

Lori ẹsun ti wọn fi kan igbakeji gomina naa, Oloye Afuyẹ pe iwe-ẹri rẹ ko kunju oṣuwọn, Onidaajọ Zadawa da a pe iwe-ẹri ti igbakeji gomina naa ko fun ajọ eleto idibo jẹ ojulowo.

Lẹyin eyi lo da ẹjọ naa nu, to si sọ pe ẹjọ yii ko ni ẹri to daju.

Ni kete ti iroyin ẹjọ naa jade ni kootu ni awọn alatilẹyin ati awọn ọmọ ẹgbẹ APC tu sita pẹlu ilu ati ijo.

 

.

Leave a Reply