Ibo gomina Adamawa: Ọjọ Tọsidee la maa kede ẹni to jawe olubori-INEC

Faith Adebọla

Awuyewuye to bẹ silẹ lori atundi idibo sipo gomina nipinlẹ Adamawa, eyi to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹrin yii ti gbọna mi-in yọ bayii, ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission, INEC, ti jawe ‘gbele ẹ, ma da sọrọ wa mọ’ fun Kọmiṣanna wọn nipinlẹ Adamawa, iyẹn REC, Amofin Hudu Yunusa-Ari, ẹni ti wọn lo kede abajade esi idibo lọna aitọ lọjọ Sannde to kọja yii, amọ oludije funpo gomina lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Abilekọ Aisha Binani Dahiru, ti wọn lọkunrin yii kede rẹ poun lo jawe olubori, toun naa si ti n dupẹ bi wọn ṣe n ki i ku oriire, obinrin yii ti kọri sile-ẹjọ, o ni kile-ẹjọ ba oun da INEC lọwọ kọ, ki wọn maṣe yii ikede oun gẹgẹ bii gomina aṣẹṣẹ-yan pada, ki wọn si tun ba oun tan’na wodi gbogbo awuyewuye to bẹ silẹ ọhun, boya eru ati ọtẹ lo wa nidi ẹ abi ki i ṣe bẹẹ.

Bakan naa ni INEC ti sọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ogunjọ oṣu Kẹrin yii lawọn maa ṣalaye lẹkun-un-rẹrẹ nipa bi eto idibo ipinlẹ Adamawa ṣe lọ si latoke dele, tawọn yoo si kede ẹni to jawe olubori sipo gomina. Wọn lawọn maa fi ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ati Ọjọbọ, Tọsidee to ṣaaju ṣe iwadii, atupalẹ, akojọ, iṣiro ati aropọ esi idibo naa, tawọn yoo si wo bii abajade naa ṣe kunju oṣuwọn alakalẹ ati ofin eto idibo si, kawọn too kede faye gbọ.

Adari eto iroyin ati ilanilọyẹ fun INEC, Ọmọwe Festus Okoye lo sọrọ yii di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Abuja, lọjọ Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin yii. Asiko naa lo sọ ọ di mimọ pe awọn ti ni ki Yunusa-Ari ti wọn lo dọwọ ru lasiko akojọ esi ibo ọhun lọọ rọọkun nile.

Amọ, ninu ẹjọ kan ti Binani pe siwaju ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Abuja, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin yii, o ni ki wọn ba oun yiiri aṣẹ ti olujẹjọ kinni, iyẹn INEC, pa lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, pe awọn wọgi le kikede ti Kọmiṣanna INEC ipinlẹ Adamawa, Hudu Yunusa-Ari, kede oun bii ẹni to gbegba oroke, ati gomina aṣẹṣẹ-dibo-yan ipinlẹ naa. O ni njẹ o bofin mu ki INEC maa kede, ki INEC maa wọgi le e, nitori ẹni to kede yii, aṣoju INEC ni.

Bakan naa lo tun fẹsun kan olujẹjọ keji ati ikẹta, iyẹn gomina ipinlẹ Adamawa lọwọlọwọ, Ahmadu Fintiri ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, Peoples Democratic Party, PDP, pe niṣe ni wọn mọ-ọn-mọ n dana ijangbọn kaakiri ipinlẹ naa, dipo ki wọn fara mọ ikede ti INEC ṣe poun ni gomina aṣẹṣẹ-dibo-yan tuntun. O ni ọtẹ ati tẹmbẹlẹkun lo mu ki wọn maa da omi alaafia ilu ru, o si rọ ile-ẹjọ lati pa a laṣẹ fun wọn ki wọn so ewe agbejẹẹ mọwọ.

Binani, nipasẹ agbẹjọro rẹ, Amofin agba Hassaini Zakariyahu, sọ pe awọn ẹbẹ toun tẹ pẹpẹ rẹ siwaju ile-ẹjọ naa wa ni ibamu pẹlu abala ọtalerugba din mẹsan-an (251) iwe ofin Naijiria ati abala okandinlaaadọjọ (149) ati ejilelaaadọjọ (152) iwe ofin eto idibo ilẹ wa ti ọdun 2022.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ Aiku, Sannde, ni ariwo ti gbode kan lori abajade atundi ibo to waye lawọn ibudo idibo mọkandinlaaadọrin kan nipinlẹ naa.

Nibi ti wọn si kede esi idibo naa de, Gomina Fintiri to ti lewaju ninu ibo ti ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹta to waye ṣaaju naa lo tun n lewaju ninu atundi idibo ti wọn ti ka laaarọ ọjọ Sannde to lọ yii.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni Ọga ajọ INEC l’Adamawa yii, Hudu Yunusa-Ali, kan ṣadeede yan bii ologun wọnu gbọngan ti wọn ti n ṣiro esi idibo lọwọ, to si bẹrẹ si i sọrọ fatafata sinu ẹrọ amohun-bu-gbẹmu pe Binani ti gbegba oroke, amọ ko sọ iye ibo ti obinrin naa ni, bẹẹ ni ko sọ pe oun laṣẹ lati ṣe ikede yii.

Ikede ọhun ti mu ki Sẹnetọ Binani ba awọn oniroyin sọrọ idupẹ, o ni inu oun dun poun yege, ati pe oun ni yoo di gomina obinrin akọkọ ninu itan orileede Naijiria, bẹẹ si lọrọ naa ti n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara.

Eyi lo mu kọrọ di iṣu-ata-yan-an-yan-an, awọn janduku kan ki Yunusa-Ali mọlẹ, wọn lu u lalubami, awọn agbofinro si tun mu un, bakan ajọ INEC ni olu ileeṣẹ wọn l’Abuja si paṣẹ pe awọn ti wọgile ikede tọkunrin yii ṣe, wọn ni ko bofin mu, wọn tun ni ki gbogbo eto akojọ esi idibo duro na, ki wọn maa ko gbogbo eto ọhun bọ l’Abuja.
Ọrọ yii ti fa ọpọ ariyanjiyan gidi, bi ẹgbẹ APC ati Binani ṣe n sọrọ, bẹẹ ni PDP ati Gomina Fintiri n ṣaroye, awọn amofin, awọn eekan oloṣelu, titi kan oludije funpo aarẹ PDP, Atiku Abubakar, ati awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in ni wọn ti fi aidunnu wọn han si iṣẹlẹ Adamawa naa.

Ibi ti ọrọ naa yoo jalẹ si bayii lawọn eeyan n duro de.

Leave a Reply