Faith Adebọla
Ọrọ ta a pe lowe to n ni aro ninu, lọrọ igbẹjọ to n lọ lọwọ lori abajade esi idibo sipo gomina ipinlẹ Ogun, latari ọkan-o-jọkan awọn ẹlẹrii ti wọn n jẹrii ta ko esi idibo ti INEC kede. Ẹlẹrii kan, Ọlalekan Ọdẹsanya, ti sọrọ soke niwaju igbimọ to n gbọ awuyewuye to su yọ nibi eto idibo ọhun pe niṣe ni wọn wọgi le ibo ti wọn di nibudo idibo awọn, latari bawọn janduku kan ṣe da gbogbo ẹ ru lọjọ idibo, ko si sẹni to ka ibo kankan, tori ko tiẹ si ibo tẹnikan le ka, o ni agbelẹrọ ati ayederu lasan ni esi ibo ibudo naa ti INEC ṣakọọlẹ rẹ, ti wọn si ka, ko si esi idibo kan pẹẹ lọjọ naa.
Ọdẹsanya jẹrii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ yii, niwaju igbimọ onidaajọ to fikalẹ sagbegbe Iṣabọ, niluu Abẹokuta.
Ẹlẹrii yii wa lara awọn ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun pe nipasẹ lọọya rẹ.
Ọkunrin naa ni ibudo idibo keji, to wa ninu ọgba ileewe Wesley Primary School, Oke-Ẹri, nijọba ibilẹ Ariwa/Ila-Oorun Ijẹbu, loun ti lọọ dibo lọjọ naa lọhun-un, o ni eto idibo naa ko ti i pari, ko si too di asiko ti ibo kika yoo bẹrẹ ni ija buruku kan ti bẹ silẹ laarin awọn oludibo ti wọn n ṣẹgbẹ ọtọọtọ, ati awọn kan ti wọn n fi kaadi ipe sori foonu (credit cards) ra ibo, n ni wọn ba da ibo ru.
O ni ara-meriyiri ni fọọmu EC8A ti wọn fi han oun ni kootu, nibi ti ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission (INEC), kọ esi idibo si pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ni ibo mọkandinlogoje (139), ti All Progressives Congress (APC), si ni ibo mẹrindinlaaadọrin (66), nitori ko si kika ibo tabi ikede esi ibo kankan to waye nibẹ lọjọ naa. “Esi idibo tẹ ẹ n fi han mi yii, feeki ni, ayederu lo maa jẹ, ko si esi idibo kankan ti wọn ka lọjọ naa.”
Agbẹjọro Ladi Adebutu, oludije gomina PDP to pe Dapọ Abiọdun ati INEC lẹjọ, Amofin agba Gordy Uche, tun fi fọọmu EC40G han ẹlẹrii yii, nibi ti INEC kọ ọ si pe idibo waye, wọn si ka ibo ni ibudo idibo ọhun, amọ Ọdẹsanya ni irọ patapata ni INEC pa.
O fi kun un pe awọn raborabo ha kaadi ipe lọjọ naa, wọn si ha a kan oun pẹlu, oun gba a, ni kia loun si ti lọọ paarọ kaadi ti wọn fun oun si owo, t’oun si ti na’wo naa.
Igbẹjọ ṣi n tẹsiwaju.